Ina tun jo eeyan marun pa ninu ijamba ọkọ ni marosẹ Eko s’Ibadan 

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta

Tanka to gbe epo bẹntiroolu lo gbina lojiji, ni nnkan bíi aago marun-un idaji ku iṣẹju mẹrinla, l’Ọjọruu,  ọjo kẹtadinlogun, oṣu kọkanla, ọdun 2021, ni marosẹ Epo s’Ibadan, eeyan marun-un si ṣe bẹẹ jona ku.

Ibi ileepo Tunji Alegi, l’Ogere, ni ijamba yii ti waye gẹgẹ bi Kọmandanti Ahmed Umar ti i ṣe ọga FRSC Ogun ṣe sọ.

O tẹsiwaju pe dẹrẹba to wa tanka epo naa lo n wa iwakuwa, oun lo n sare buruku ti fi lọọ lari mọ tirela to n bọ, bi ina ṣe ṣẹ yọ niyẹn, to si n jo lala. To tun ran awọn ọkọ mi-in.

Nibi tina ọhun ti n jo yii lo ti jo eeyan marun-un pa bi Umar ṣe wi, ko sẹni to ri wọn gba silẹ, afi nigba ti wọn jona tan raurau kọja idanimọ. Inu ọkan ninu awọn ọkọ to jona ọhun ni wọn ti pada ri oku wọn.

Ṣaaju niroyin ti kọkọ gbode pe mọto marun-un lo jona ninu iṣẹlẹ yii, ti awọn ẹṣọ alaabo n sọ pe kawọn eeyan ṣe ọna gba, ki wọn ma gba ibudo ijamba naa. Lẹ́yìn eyi ni wọn ṣẹṣẹ ri oku awọn to jona.

Wọn ti ko awọn oku naa lọ si mọṣuari FOS, n’Ipara.

E oo ranti pe lọsẹ to kọja yii leeyan meje lo jona ku loju ọna Marosẹ yii kan naa.

Leave a Reply