Faith Adebọla
Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣeleri fawọn agbaagba ilẹ Ibo lati iha Guusu/Ila-Oorun Naijiria pe oun maa ṣagbeyẹwo ẹbẹ wọn lati tu gbajugbaja ajijangba ilẹ Ibo nni, Ọgbẹni Nnamdi Kanu, silẹ laipẹ.
Ọrọ yii waye ninu ipade nla kan tawọn eeyan jannkan jannkan lati agbegbe naa ṣe pẹlu Buhari lọjọ Ẹti, Furaidee yii, lasiko abẹwo wọn si ile ijọba, l’Abuja, olu-ilu ilẹ wa. Aṣofin ati minisita feto igboke-gbodo ọkọ ofurufu (Aviation) nigba kan, Oloye Mbazulike Amaechi, ẹni ọdun mẹtalelaaadọrun-un (93), lo ṣaaju wọn.
Awọn agbaagba naa, ti wọn pera wọn ni ‘Awọn agbaagba ẹni ọwọ ju lọ nilẹ Igbo’ (Highly Respected Igbo Greats) tilẹkun mọri ṣepade pẹlu Aarẹ fun bii wakati kan gbako, wọn ni pataki ọrọ ti wọn ba wa ni iṣoro eto aabo to n gogo si i lagbegbe ilẹ Ibo, ati ọrọ awọn ajijangbara IPOB ti wọn lawọn n ja fun yiya orileede Biafra kuro lara Naijiria ati idasilẹ olori wọn, Ọgbẹni Kanu.
Gẹrẹ tipade naa pari ni Oludamọran pataki si Aarẹ lori eto iroyin ati ipolongo, Ọgbẹni Fẹmi Adeṣina, ti fi atẹjade lede lori lajori ipade naa, o ni lẹyin ti Buhari ti gbọ ọrọ ati ẹbẹ awọn agbaagba naa tan, o sọ fun wọn pe ibeere ka-n-ka ni ẹbẹ wọn lori ọrọ Nnamdi Kanu, ṣugbọn oun maa ṣiṣẹ lori ẹ sibẹ, lati jẹ ki alaafia pada bọ sipo lagbegbe ilẹ Ibo, kawọn ọdọ tinu n bi si lọọ fọkan lelẹ.
Buhari sọ fun wọn Oloye Amaechi pe: “Ẹbẹ ka-n-ka to kaayan laya ni ẹbẹ tẹẹ waa bẹ mi yii gẹgẹ bii olori orileede yii, ohun tẹẹ fẹ ki n ṣe yii lagbara gidi. Lati ọdun mẹfa ti mo ti wa lori aleefa iṣakoso orileede yii, ko sẹni to le naka abuku si mi pe mo da sọrọ ile-ẹjọ tabi igbẹjọ to n lọ lọwọ ri. Ṣugbọn Ọlọrun ti fun yin ni iru laakaye yii, o si ti pa yin mọ pẹlu ọpọlọ pipe, tori awọn mi-in ti o ju idaji ọjọ-ori yin lọ sibẹ ti wọn o mọ eyi to kan, tori bẹẹ, ma a ṣiṣẹ lori ẹbẹ yin, ma a ronu lori ẹ daadaa.”
Fẹmi ni Baba arugbo kujọkujọ naa, Amaechi, parọwa pe ki Buhari yọnda Nnamdi Kanu foun, ko si fọrọ rẹ ya oun, ki wọn yanju awọn ẹsun ti wọn ka si i lọrun nitubi-inubu lọna ti oṣelu dipo ti ologun, Buhari si ti ṣeleri pe oun yoo wa nnkan ṣe si i.
Lara awọn eeyan nla nla ti wọn wa nipade naa ni Gomina ipinlẹ Anambra nigba kan, Oloye Chukwuemeka Ezeife, Biṣọọbu agba ijọ Mẹtọdiisi, Sunday Onuoha, Amofin Goddy Nwazurike, Aarẹ ẹgbẹ awọn agba ilẹ Ibo tẹlẹ, Aka Ikenga, ati awọn agbaagba mi-in.