Faith Adebọla
Alaye ohun tawọn gende meji atawọn ọmọde mẹta yii ro ti wọn fi lọọ tu ina ẹlẹntiriiki kuro lori transifọma to wa lagbegbe Lapai-Gwari, nipinlẹ Niger, ti wọn si gbe ẹrọ amunawa ọhun pẹlu awọn waya rẹ, lo ku ti wọn n ṣe lọwọ lakolo awọn agbofinro ti wọn wa bayii.
Orukọ ati ọjọ-ori awọn maraarun ni Suleiman Zubairu, ọmọọdun mẹrindinlogun (16), Mustapha Umar ati Mande Magaji tawọn mejeeji jẹ ẹni ọdun mẹtadinlogun (17), Hussaini Adamu, ẹni ọdun mẹtalelogun (23), ati Salisu Usman, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn (25). Wọn laduugbo Kasunwa-Gwari, niluu Minna, nipinlẹ ọhun, ni gbogbo wọn n gbe.
DSP Wasiu Abiọdun to jẹ Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa sọ pe opin ọsẹ to kọja lọwọ awọn ọlọpaa ẹka Chachanga tẹ awọn afurasi naa nigba ti wọn n ṣe patiroolu, wọn ba awọn afurasi ole naa nibi ti wọn ti n ṣeto lati gbe ẹru ole nla naa lọ, o ni Salisu Usman lo gba awọn waya naa lọwọ wọn lati ba wọn ta a.
Abiọdun ni bi wọn ṣe ko wọn de teṣan ọlọpaa lawọn afurasi naa ti n ka boroboro pe loootọ lawọn ji transifọma ati waya atawọn eroja abanaṣiṣẹ ti wọn ba lọwọ wọn. Wọn tun jẹwọ pe transifọma keji tawọn n tu lọwọ ni wọn ka awọn mọdii ẹ yii.
Alukoro ọlọpaa ni iwadii ṣi n tẹsiwaju lori wọn, gbogbo wọn lo si maa foju bale-ẹjọ. O lẹsun ole jija, idigunjale ati igbimọ lati huwa ọdaran lawọn maa fi kan wọn. O tun gba awọn araalu lamọran lati maa ṣọ ẹrọ amunawa to ba wa laduugbo wọn.