Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Bo tilẹ jẹ pe inu ibanujẹ nla ni awọn mọlẹbi kan to padanu gbogbo dukia wọn ninu ijamba ina kan to ṣẹlẹ lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, l’Opopona Hassan Olowo, lagbegbe Sango, niluu Ilọrin, ṣi wa, awọn mọlẹbi naa ti fidi ẹ mulẹ pe ina mọnamọna to ṣẹju lo ṣokunfa ijamba naa.
Ọkan lara awọn mọlẹbi to ba ALAROYE sọrọ fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni bi ina ẹlẹntiriiki naa ṣe ṣẹju ni eefin bẹrẹ si i ru ni bii ọgbọn iṣẹju. Awọn kan si ajọ panapana, ṣugbọn wọn o tete dahun, awọn tun sare lọ si ọfiisi ajọ naa, ṣugbọn wọn ko si nibẹ. Ni kukuru, gbogbo dukia to wa ninu ile naa lo jona, ti wọn ko si ri nnkan kan mu jade ninu ile ọhun.
Awọn mọlẹbi naa ni ọpẹ ni fun Ọlọrun pe ko ṣeni to ku ninu iṣẹlẹ naa, bo tilẹ jẹ pe obitibiti owo ati dukia lo ṣegbe, ina jo wọn run gburugburub aṣọ ẹyọ kan lo kere jub wọn o ri mu jade. Wọn ti waa rawọ ẹbẹ sawọn ẹlẹyinju aanu ati ijọba ipinlẹ Kwara lati dide iranwọ, nitori awọn ko nile lori mọ bayii.