Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Adegboyega Oyetọla, ti sọ pe pẹlu awọn oniruuru nnkan alumọọni ti Eledua fi jinki awọn eeyan Iwọ-Oorun orileede yii, ko yẹ kipinlẹ kankan nibẹ ṣe alaini awọn nnkan to yẹ fun idagbasoke.
Lasiko ti gomina n ṣide ipatẹ nnkan ọgbin atawọn ohun alumọọni fun awọn ipinlẹ apa Iwọ-Oorun (South-West Local Governments Agriculture and Mineral Resources Trade Fair) eleyii ti ileeṣẹ to n ri si ọrọ okoowo, ileeṣẹ, kusa ati nnkan ọgbin ṣagbekalẹ rẹ niluu Oṣogbo, lo ti sọrọ yii.
O ni eto ipatẹ naa bọ si akoko pupọ nitori o waye ni bayii tijọba apapọ ti n lọgun lori awọn ọna miiran ti eto ọrọ-aje fi le rugọgọ si i kaakiri orileede yii.
Oyetọla, ẹni ti igbakeji rẹ, Benedict Alabi, ṣoju fun ṣalaye pe lasiko yii ti owo to n wọle latibi epo rọbi ti dẹnukọlẹ, o pọn dandan ki gbogbo ipinlẹ gbe ọkan kuro nibẹ si awọn nnkan to le mowo wọle ju epo-rọbi gan-an lọ.
O sọ pe ipatẹ-owo naa, eleyii to n waye lẹyin ọdun mẹtadinlogun to ti waye gbẹyin wa lati ta awọn eeyan iha Iwọ-Oorun ji, ki wọn ronu jinlẹ, ki wọn si lo anfaani nnkan ọgbin atawọn nnkan alumọọni to wa lagbegbe wọn daadaa lati mu igbega ba owo ti wọn yoo maa ri labẹnu.
Oyetọla ṣalaye pe owo gọbọi lo wa nidii iṣẹ ọgbin atawọn nnkan alumọọni, paapaa, ti wọn ba n ko wọn ranṣẹ si oke-okun, o si rọ wọn lati lo anfaani naa fun ipese iṣẹ fun awọn araalu.
O ni “Iwadii ti fihan pe ipinlẹ kọọkan ni, o kere tan, nnkan alumọọni mẹrin-mẹrin, o si daju pe awọn ipinlẹ ilẹ Yoruba yoo ni ju bẹẹ lọ.
“Eleyii fi han pe ko yẹ ka toṣi tabi ṣe alaini. O tun tumọ si pe o ku si wa lọwọ lati lo awọn nnkan yii fun anfaani wa.
“Ohun ti a n reti nipasẹ ipatẹ yii ni ki ọrọ-aje wa lagbegbe yii burẹkẹ si i, ki awọn nnkan ti Ọlọrun fi jinki wa si di mimọ fun gbogbo agbaye ri”