Ọmọ ẹgbẹ okunkun meji fipa fa akẹkọọ Ọlabisi  Ọnabanjọ Yunifasiti wọ ẹgbẹ Ẹyẹ n’Ijẹbu-Igbo

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun lawọn ọmọkunrin meji yii, orukọ wọn ni  Owoṣeni Gbemisọla ati  Ogunṣọla Ayọ.

Ọjọ Ẹti to kọja yii lawọn ọlọpaa Ago-Iwoye mu wọn, lẹyin ti akẹkọọ kan fẹjọ wọn sun pe wọn fipa mu oun wọnu ẹgbẹ okunkun Ẹyẹ tawọn ọmọkunrin meji yii n ṣe.

Atẹjade DSP Abimbọla Oyeyẹmi to fiṣẹlẹ naa sita lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ṣalaye pe ọmọ ọdun mọkanlelogun pere ni akẹkọọ tawọn ọmọ yii fipa fa wọnu ẹgbẹ wọn.

O ni ọmọ naa to jẹ akekọọ ileewe Ọlabisi Ọnabanjọ Yunifasiti lo lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa Agọ Iwoye, pe ẹnikan torukọ ẹ n jẹ Yẹmi Justice, ti inagijẹ rẹ n jẹ JP lo tan oun lọ s’ijẹbu-Igbo.

O ni Yẹmi sọ foun pe ibi tawọn yoo ti riṣẹ diẹ ṣe kawọn le lowo lọwọ loun n moun lọ n’Ijẹbu-Igbo. Afi bawọn ṣe debẹ ti Yẹmi pẹlu Owoṣeni ati Ogunṣọla fi aṣọ bo oun loju, ti wọn lu oun bii ejo aijẹ, ti wọn si fipa sọ oun di ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹyẹ.

Ifisun rẹ yii lo jẹ kawọn ọlọpaa bẹrẹ si i dọdẹ awọn to tan an wọ ẹgbẹ naa, ko si pẹ ti wọn fi ri Owoṣeni Gbemisọla mu nibi to ti n dunkooko mọ akẹkọọ ti wọn forukọ bo laṣiiri naa, to n sọ pe dandan ni ko darapọ m’ẹgbẹ awọn.

Bi wọn ṣe ri i mu lo ṣokunfa mimu ti wọn mu Ayọ Ogunṣọla ti i ṣe ẹnikeji rẹ naa, ṣugbọn Yẹmi Justice to jẹ ẹnikẹta wọn sa lọ ni tiẹ, awọn ọlọpaa ṣi n wa a.

CP Lanre Bankọle ti paṣẹ pe ki wọn ko awọn meji yii lọ sẹka itọpinpin, ki wọn si ko wọn lọ si kootu laipẹ.

Leave a Reply