Ọlawale Ajao, Ibadan
Igbakeji Aarẹ orileede yii, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo ti rọ awọn Yoruba lati ṣeto bi wọn yoo ṣe ri awọn ohun isẹnbaye wọn ti wọn ti ji gbe lọ atawọn ti wọn gbe lọ lọna to bofin mu gba pada.
Nibi ifilọlẹ Ibudo Agbaye fun itọju awọn nnkan aṣa ati ohun isẹnbaye Yoruba ti wọn pe ni International Centre for Yoruba Arts and Culture, eyi to waye lọjọ Iṣẹgun,Tusidee, ọjọ kẹtalelogun, (23) oṣu kọkanla, ọdun 2021 yii, lo ti sọrọ naa ninu ọgba Fasiti Ibadan.
Ọṣinbajo sọ pe “Ẹ gbọdọ wa ọna lati jẹ ki awọn ohun iṣẹnbaye ti wọn ti ji gbe lọ silẹ okeere pada sile, bo tilẹ jẹ pé a kò mọ bí wọn ṣe n poora. A le ko awọn nnkan wọnyi pamọ sinu gbọngan yii paapaa.
Awon gomina ilẹ Yoruba bii Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde tipinlẹ Ọyọ, Arakunrin Rotimi Akeredolu tipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Dapọ Abiọdun tipinlẹ Ogun ni wọn ran igbakeji wọn lati ṣoju wọn nibi ayẹyẹ naa.
Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyemi kẹta, lo ṣaaju awọn ọba alade to kopa ninu eto ọhún.
Lara awọn leekan leekan to wa nibẹ ni Aarẹ Ọna-Kakanfo Ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams; ọga agba fun ajọ to n ri si idagbasoke Iwọ-Oorun Guusu orileede yii, Ọgbẹni Ṣẹyẹ Oyelẹyẹ; Ọgbẹni Adewale Raji ti i ṣe alakooso ileeṣẹ olokoowo ilẹ Yoruba nni, Odua Investment, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Awọn gomina mẹtẹẹta yii lo panu pọ rọ awọn oludasilẹ gbọngan naa lati yago gedegede si yiyi ododo itan Yoruba pada, ki wọn ma ṣe fi eto naa ṣe ṣe oṣelu rara, nitori pe Ile aṣa yii wa fun lati ṣagbega iṣọkan iran Yoruba ati lati fẹsẹ ajọṣepọ orileede wa lapapọ mulẹ ni.
Ninu ọrọ ọba nla naa, Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi, to tun jẹ Alaga eto naa, o kin Ọjọgbọn Ọṣinbajo lẹyin. O tẹsiwaju pe awọn amunisin ti dabaru awọn itan ilẹ Yoruba, leyii ti ko jẹ kawọn iran to n bọ le ri awọn itan Ilẹ Yoruba to rẹwa.
Nigba ti Iba Gani Adams n sọrọ ninu ifọrọwerọ pẹlu awọn oniroyin nipa eto naa, o ni a ni lati maa ṣakọsilẹ ati itọju itan atawọn ohun isẹnbaye wa, bi bẹẹ kọ, awọn ọta wa yoo ji wọn ko lọ, eyi yoo si ṣakoba fun idagbasoke iran Yoruba.
Ẹni to ni afojusun eto naa, Ọgbẹni Alao Adedayọ, to tun jẹ Oludasilẹ ileeṣẹ iweeroyin ALAROYE, sọ pe ala gbọngan awọn ohun isẹnbaye fun iran Yoruba kọkọ waye lọdun 2014 pẹlu erongba lati da ibi ti awọn oluwadii yoo ti maa pari iwadii wọn nipa itan, aṣa ati iṣe awọn Yoruba.
Ọga awọn ALAROYE fi kun un pe ibudo INCEYAC yii yoo ṣe iranlọwọ pupọ lati ṣagbega fun iṣelọjọ aṣa, iṣe, ẹsin ati irinajo afẹ iran ọmọ Oodua.