Ọlawale Ajao, Ibadan
Gomina ipinlẹ Ọyọ nigba kan ri, Sẹnetọ Rashidi Adewolu Ladọja, ti padanu aburo rẹ kan, Alhaji Lateef Ladọja to tun jẹ ọkan ninu awọn ololufẹ ẹ nidii oṣelu.
Lalẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, la gbọ pe Alhaji Ladọja, ẹni tọpọ eeyan tun mọ si Baba Kekere jade laye.
Ọgọọrọ awọn eekan ilu lo ti ranṣẹ ibanikẹdun si Sẹnetọ Ladọja, to tun jẹ Osi Olubadan tilẹ Ibadan.
Lara wọn l’Amofin-Agba Niyi Akintọla, ẹni to ṣapejuwe oloogbe naa gẹgẹ bii oniwa tutu bii adaba nigba aye ẹ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Nigbati ta a gbọ pe iku ti ja oniwa tutu bii adaba yii gba mọ wa lọwọ, ibeere to koko wa sẹnu gbogbo wa ni pe, ki lode to jẹ Ladọja niku mu lọ, ki lo ṣẹlẹ gan-an?
“Sugbon ta ni wa lati ba Ọlọrun Ọba wijọ nipa igba ti yoo mu ẹda ọwọ ẹ lọ nigba to ba wu u.”
Agba Amofin naa waa gbadura pe ki Ọlọrun fi alijanna onidẹra jinki oloogbe naa, ko si fun gbogbo ẹbi ẹ lẹmi-in itẹmọra lati le gba iku baba kekere bi amuwa Ọlọrun.
Ninu ọrọ ibanikẹdun tiẹ, Oludije fun ipo gomina ipinlẹ Ọyọ, Mọgaji Joseph Tegbe, gba pe aiduro deede eto aabo orileede yii lo ṣokunfa iku aburo Ladọja.
Ọ ni, “Mo ba Agba-Oye Rashidi Adewọlu Ladọja kẹdun iku aburo wọn to tun jẹ ọkan ninu awọn alatilẹyin wọn. Ki Ọlọrun ba ni tu idile wọn ninu.
“Iṣẹlẹ iku Baba kekere lo tun mu wa ranti idi to ṣe ṣe pataki ki awọn ijọba wa wa nnkan ṣe sọrọ eto aabo kiakia, nitori a o le ṣe bayii maa padanu awọn eeyan pataki sọwọ iku ti ki i ṣe afọwọ-rọri-ku”.