Agba oloṣelu apa Oke-Ọya ilẹ wa kan, to tun jẹ agba ẹgbẹ Arewa Consultative Forum, Alaaji Tanko Yakassai ti ṣi’ṣọ loju eegun ifẹ ọkan Aṣiwaju Bọla Tinubu, o ni Tinubu fẹẹ dupo aarẹ lọdun 2023, ọrọ nipa boun (Yakassai) ṣe maa ṣatilẹyin fun un lati de ipo naa lo waa ba oun sọ l’Abuja.
Tanko sọrọ yii lọjọ Ẹti, Furaidee ọsẹ yii, fun akọroyin Punch to bi i leere lajori ọrọ toun ati Tinubu sọ lasiko ti gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ naa ṣabẹwo sọdọ rẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee.
Ọkunrin naa ni bo tilẹ jẹ pe oun o ni in lọkan lati tun pada sidii aayan oṣelu mọ, sibẹ, oun ṣi lanfaani lati tẹle ẹnikẹni tọkan oun ba yan, toun si mọ pe o le tukọ ijọba Naijiria de ebute ogo, o lawọn meji lo wa lọkan oun, oun si ti pinnu pe ẹni to ba kọkọ waa ba oun sọrọ loun maa duro ti, o loun maa ṣatilẹyin fun Tinubu lọtẹ yii.
“Tinubu kan waa ki mi, ṣugbọn o ba mi ṣọrọ lori erongba rẹ lati jade dupo aarẹ ninu eto idibo to n bọ yii. Loootọ, eeyan meji lo wa lọkan mi latilẹ, mo si ti sọ pe ẹni to ba kọkọ waa ba mi ninu awọn mejeeji ni maa ṣatilẹyin fun. Tinubu lo kọkọ waa ba mi.”
Nigba ti wọn bi i pe ṣe Tinubu fẹnu ara ẹ sọ pe oun fẹẹ jade dupo aarẹ ni, Yakassai fesi pe bẹẹ ni, o sọ bẹẹ fun mi, o si ni ki n ṣatilẹyin foun.
Ṣugbọn lori didarapọ mọ ẹgbẹ oṣelu lakọtun, Yakassai ni “mi o tun ṣe aayan eto oṣelu mọ, mi o si ni i di ọmọ ẹgbẹ oṣelu kan, ṣugbọn ondije eyikeyii to ba wu mi ni mo le tẹle, ibẹ naa si lawọn alatilẹyin mi n lọ. Lati ọdun 1951 ni mo ti pinnu pe mi o ni i ṣẹgbẹ oṣelu, mi o si ti i yi ipinnu naa pada.”
Tẹ o ba gbagbe, ọpọ awuyewuye lo waye latari bawọn eeyan ṣe n gbe oriṣiiriṣii ẹgbẹ ipolongo dide lati ṣatilẹyin fun Adari ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress (APC), Aṣiwaju Bọla Tinubu, lati dije fun ipo aarẹ lọdun 2023. Eyi to lewaju ninu awọn ẹgbẹ naa ni eyi ti wọn n pe ni SWAGA ’23, iyẹn South-West Agenda 2023, eyi ti Gomina Babajide Sanwo-Olu tipinlẹ Eko ṣefilọlẹ rẹ niluu Eko loṣu kẹwaa, ọdun yii, ti wọn si ti n ṣefilọlẹ ẹgbẹ naa kaakiri awọn ipinlẹ ilẹ Yoruba.
Ṣugbọn latari bi Tinubu funra rẹ ko ṣe ti i sọ erongba rẹ di mimọ, eyi lo n fa ariyanjiyan boya ọkunrin naa fẹẹ dupo aarẹ loootọ abi awọn olulufẹ rẹ lo wulẹ n ṣiṣẹ fun un.
Ọsẹ to kọja yii ni Gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ, Babatunde Raji Faṣọla, to jẹ Minisita fun iṣẹ ode ati ile gbigbe sọ pe o di inu oṣu ki-in-ni, ọdun to n bọ, ki Tinubu too fẹnu ara ẹ sọ ibi toun n lọ faraye.
Amọ, pẹlu alaye ti Tanko Yakassai ṣe yii, ko si iyemeji mọ ninu erongba Tinubu lati dupo aarẹ Naijiria lọdun 2023.