Akẹkọọ to ba tapa sofin yoo balẹ sile awọn ọmọ alaigbọran- Arigbabu

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Kọmiṣanna eto ẹkọ, Sayẹnsi ati Imọ ẹrọ nipinlẹ Ogun, Ọjọgbọn Abayọmi Arigbabu, ti jẹ ko di mimọ pe akẹkọọ yoowu to ba kọja aaye ẹ nipinlẹ yii yoo fẹsẹ kan de ile ti wọn n tọju awọn ọmọ alaigbọran si, (Juvenile Home), wọn yoo si da a duro sibẹ titi ti yoo fi kọ ẹkọ nipa jijẹ ọmọluabi.

Ọjọgbọn Arigbabu sọrọ yii lasiko to lọọ ki Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle, latari ọkan ninu awọn DPO rẹ tawọn akẹkọọ ileewe Aṣero High School, ati Ẹgba Comprehensive High School, foko fọ lori, nigba ti ọkunrin naa atawọn ọmọọṣẹ rẹ lọọ pẹtu saawọ awọn akẹkọọ ọhun l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja.

Kọmiṣanna sọ pe iṣẹlẹ naa buru jai, oun si wa lati tọrọ aforiji, koun si tun ba awọn ọlọpaa kẹdun ni.

O ni gbogbo idaniloju pata loun fi n sọrọ naa, pe akẹkọọ yoowu to ba yaju si olukọ tabi to huwa ọmọ ganfe lati isinyii lọ yoo de atimọle awọn ọmọde, ijọba ko ni i wo ti ọjọ ori rẹ ti wọn yoo fi da sẹria to ba yẹ fun un nipa gbigbe e lọ sahaamọ.

O waa dupẹ lọwọ awọn ọlọpaa fun bi wọn ṣe ri aawọ naa yanju pẹlu ohun to ṣẹlẹ si wọn naa.

Ninu ọrọ tirẹ, CP Lanre Bankọle sọ pe ojuṣe ọlọpaa ati ileeṣẹ eto ẹkọ ni lati ri si ọrọ awọn akẹkọọ yii. O ni gbogbo igba lawọn n wa lakọ bii ibọn lati pẹtu saawọ yoowu to ba ti ọdọ awọn akẹkọọ naa wa.

Leave a Reply