Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ẹni ọdun mejidinlọgọrin ( 78) ni baba ti ẹ n wo yii, Mọshood Habibu lorukọ ẹ. Niṣe lo fi ada ṣa ẹgbọn ẹ, Alagba Salisu Surakatu to jẹ ẹni ọdun mẹrinlelaaadọrun-un (94) pa mọle ni Mowe, ipinlẹ Ogun, nitori ilẹ to ni oloogbe naa ta ti ko foun lara owo ẹ.
Ọmọ oloogbe, Aminu Salisu, lo lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa Mowe, pe l’Ọjọruu, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kọkanla yii, aburo baba oun, Mọshood Habibu, wa sile ẹgbọn ẹ ti i ṣe baba toun, labule Kara Ewumi, o si ṣa baba oun ladaa pa nitori ọrọ ilẹ.
Awọn ọlọpaa tẹle ọmọ to fẹjọ sun naa lọ sile baba rẹ, wọn ba Habibu nibẹ, wọn si mu un.
Nigba ti wọn fọrọ wa a lẹnu wo, baba to ṣa ẹgbọn ẹ pa naa ṣalaye pe ẹgbọn oun ta pulọọti kan ninu ilẹ mọlẹbi awọn, o si n da na owo ilẹ naa, ko foun lẹtọọ toun ninu ẹ.
O tẹsiwaju pe owo to jẹ ẹtọ oun ninu owo ilẹ ọhun loun tori ẹ waa ba ẹgbọn oun laaarọ ọjọ naa, eyi lo si di ariyanjiyan to fi di a n ṣara ẹni ladaa.
Iwadii awọn ọlọpaa fi han pe ki Habibu too kuro nile tiẹ lo ti mu ada ti yoo fi ṣọṣẹ naa dani, nigba to si de ile ẹgbọn rẹ to ti darugbo, ti ko si riran daadaa mọ naa, niṣe lo bẹrẹ si i ṣa a ladaa nigba ti oloogbe naa n sọ fun un pe ko jade kuro nile oun.
Bo ṣe pa baba arugbo naa tan tọwọ si ti ba a lawọn ọlọpaa ti gbe e lọ sẹka to n ri si ipaniyan, wọn yoo ṣewadii lẹnu rẹ siwaju, wọn yoo si gbabẹ gbe e lọ si kootu lati jẹjọ ipaniyan.