Awọn agbebọn to ji tiṣa mẹrin gbe l’Akoko n beere fun miliọnu mẹrin Naira

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn agbebọn to ji olukọ agba kan, igbakeji rẹ atawọn olukọ meji abẹ rẹ gbe l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja yii, la gbọ pe wọn ti n beere fun miliọnu mẹrin Naira ki wọn too tu wọn silẹ kuro ninu igbekun wọn.

Miliọnu marundinlogoji Naira lawọn ajinigbe naa kọkọ beere fun nigba ti wọn kan si awọn ẹbi wọn lọjọ Ẹti, Furaidee, lẹyin ọpọlọpọ ẹbẹ ni wọn lawọn janduku ọhun too gba ki ẹnikọọkan wọn san miliọnu kan Naira gẹgẹ bii owo itusilẹ wọn.

Ohun ta a gbọ ni pe ṣe lawọn ajinigbe naa kọ jalẹ lati ba Abilekọ Hellen Adeyẹmi to jẹ iyawo olukọ agba naa sọ ohunkohun, ohun ti wọn sọ fun un ni pe awọn ko fẹẹ ni nnkan i ṣe pẹlu obinrin, wọn lawọn ọkunrin nikan lawọn fẹẹ ba sọrọ.

Apapọ ẹgbẹ awọn olukọ agba ileewe girama nipinlẹ Ondo ti fi ẹdun ọkan wọn han lori bi awọn olukọ mẹrẹẹrin ṣe wa ninu igbekun awọn ajinigbe lati bíi ọjọ mẹta sẹyin lai ni ireti ọjọ ti wọn fẹẹ gba ominira.

Wọn ni ẹbẹ lawọn n bẹ awọn ajinigbe naa ki wọn siju aanu wo awọn ọmọ ẹni-ẹlẹni to wa ninu igbekun wọn, bakan naa ni wọn tun rọ ijọba lati gbe igbesẹ to yẹ lasiko.

Ọga agba fawọn ọlọpaa n’Ikarẹ Akoko, SP Akintujoye Akinwande, ni awọn ṣi n tẹsiwaju lati maa lepa awọn ọdaran ọhun ki wọn le ri awọn ti wọn ti ji gbe lọ naa gba pada lai fara pa.

 

 

Leave a Reply