Faith Adebọla, Eko
Oludamọran pataki fun Gomina Babajide Sanwo-Olu lori ọrọ kolẹ-kodọti ati pipa ofin imọtoto mọ (LAWMA), Ọgbẹni Ayọ Williams, ti doloogbe.
Willy, gẹgẹ bawọn ololufẹ rẹ ṣe maa n pe e, jade laye lalẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kọkanla yii, lẹyin aisan ranpẹ.
Ọga kan lẹka ileeṣẹ LAWMA ti ko fẹ ka darukọ oun fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni lati ọjọ diẹ sẹyin ni ọkunrin naa ti n ṣaarẹ, bo tilẹ jẹ pe ko sọ pato iru aisan to n ṣe e. O ni Willy ko le wa sọfiisi lopin ọsẹ to lọ yii.
Bakan naa ni Abilekọ Ṣade Kadiri, Alukoro ileeṣẹ LAWMA, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, ṣugbọn o loun o ti i le ṣe ẹkunrẹrẹ alaye nipa rẹ.
Titi dasiko iku rẹ, Williams ni Baṣọrun ilu Yaba, o si jẹ ọkan ninu awọn agba ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress l’Ekoo.