Gumi yari: Emi o ni i ba yin bẹbẹ lọdọ awọn agbebọn mọ o

Faith Adebọla

Latari bi ile-ẹjọ ṣe kede pe awọn janduku agbebọn ti wọn huwa ọdaran kaakiri orileede yii ki i ṣe agbebọn lasan, afẹmiṣofo ni wọn, ọwọ afẹmiṣofo ni kijọba si fi mu wọn, ilumọ-ọn-ka aṣaaju ati olukọ ẹsin Musulumi lapa Oke-Ọya ilẹ wa, Sheikh Ahmed Abubakar Gumi, ti loun o ni i ṣeranwọ kan nipa awọn eeṣin-o-kọ’ku naa funjọba mọ, bẹẹ loun o si ni i ba ẹnikẹni bẹ wọn, tabi ba wọn sọrọ mọ.

Gumi sọrọ yii lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, nigba to n dahun ibeere ti ileeṣẹ tẹlifiṣan TVC bi i nipa ero rẹ lori aṣẹ ile-ẹjọ naa.

Tẹ o ba gbagbe, ile-ẹjọ giga apapọ kan niluu Abuja ti kede lọjọ Ẹti, Furaidee yii, pe aito eyin i ka ni ka fọwọ bo o, adape ole ni ka sọ pe ọmọ n fẹwọ, o ni orukọ to ba iwa tawọn janduku agbebọn n hu gan-an ni lati pe wọn ni afẹmiṣofo eeṣin-o-kọku ẹda, o si kede wọn bẹẹ.

Ile-ẹjọ naa ni awọn iwa bii ijinigbe, ipaayan, ifipabanilopọ, ilọnilọwọgba ati fifi ibọn ṣe ni leṣe tabi ki wọn yinbọn paayan bii ẹran, ijinigbe lati fi wọn pa’wo, ijinigbe lati fi wọn ṣ’aya, jiji awọn ọmọleewe rẹpẹte gbe wọ’gbo, jiji maaluu ko, sisọ awọn eeyan di ẹru, sisọ awọn eeyan sahaamọ, pipọn awọn eeyan loju, didana sun dukia ati awọn iwa bẹẹ to n waye lapa Ariwa/Ila-Oorun, Aarin-Gbungbun Ariwa ati awọn agbegbe mi-in lorileede yii, fihan pe afẹmiṣofo ati eeṣin-o-kọ’ku gidi lawọn ọdaran yii.

Ṣugbọn ikede yii ko dun mọ Sheikh Gumi ninu rara, ko si fi pamọ, o sọ ero rẹ jade pe ikede naa ko le tu irun kan lara awọn afẹmiṣofo ọhun, o lo tubọ maa mu iwa wọn buru si i ni, tori ohun to ṣẹlẹ nigba tijọba kede awọn ọmọ ẹgbẹ IPOB to n ja fun idasilẹ orileede Biafra gẹgẹ bii afẹmiṣofo niyẹn, niṣe lo tubọ fa wahala si i.

Ninu fọran fidio to ti sọrọ lọjọ Aje, Gumi ṣalaye idi toun o fi ni i ṣeranwọ funjọba tabi ẹnikẹni lati ba awọn ọdaran naa sọrọ mọ, o ni:

“Ko yẹ ka sun awọn janduku wọnyi kan ogiri, ko yẹ ka jẹ ki wọn yari mọ wa lọwọ, tori wọn le yari, ki wọn si ṣọṣẹ ju bi wọn ti n ṣe yii lọ. Ki lo de tijọba lọọ n sare pe wọn ni afẹmiṣofo, nigba ti wọn ṣi lawọn fẹẹ ba wọn sọrọ nitunbi-inubi?

Awa ojiṣẹ Ọlọrun nikan naa la too ba wọn sọrọ, ṣugbọn iyẹn o ṣee ṣe mọ bayii. Emi o ni i lọọ ba wọn sọrọ mọ o, tori mi o fẹ kẹnikan sọ pe mo n ṣagbodegba fawọn afẹmiṣofo.”

Bẹẹ ni Gumi wi.

Leave a Reply