Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ileewe girama mejila nijọba ipinlẹ Ogun ti paṣẹ pe wọn gbọdọ lọ si isinmi apapandodo bayii, bẹrẹ lati ọjọ Iṣẹgun, ọgbọnjọ, oṣu kọkanla, ọdun 2021 yii, nitori awọn iwa jagidijagan ti wọn n ka mọ awọn akẹkọọ naa lọwọ.
Kọmiṣanna fun eto ẹkọ, Sayẹnsi ati Imọ ẹrọ, Ọjọgbọn Abayọmi Arigbabu, lo sọ eyi di mimọ lọjọ Iṣẹgun naa ninu lẹta to kọ sawọn alakooso ileewe lẹkun ipinlẹ Ogun.
Awọn ileewe ti isinmi ojiji naa kan ni: Egba High School, Asero High School, Itori Comprehensive High School, Ofada Community Comprehensive High School, Lafẹnwa High School.
Awọn yooku ni Egba Owode Grammar School, Community Comprehensive High School, Ijoun, Unity High School, Kajọla Ibooro, Ado-Odo-Ọta ati Eyinni Comprehensive High School, Ibooro.
Liṣabi Grammar School naa wa nibẹ, pẹlu Government Science & Technical College ati Methodist High School, Arigbajo.
Tẹ o ba gbagbe, awọn akẹkọọ kan ninu awọn ileewe tọrọ kan yii gbe ileewe naa jade saye pẹlu iroyin buruku laipẹ yii.
Awọn kan sọko fọ DPO lori, awọn kan lawọn yoo pa tiṣa, bẹẹ lẹsun awọn mi-in ni i ṣe pẹlu ẹgbẹ okunkun.
Gbogbo eyi lo jẹ ki aṣẹ wa latoke, pe kawọn ileewe naa bẹrẹ isinmi tiwọn kia lẹyin idanwo saa ikẹkọọ ( first term) ti wọn pari lọjọ Iṣẹgun, ọgbọnjọ, oṣu kọkanla, naa.
Ọjọ kẹwaa, oṣu kejila, ọdun 2021, ni awọn ileewe yooku nipinlẹ Ogun, yoo too gba ọlude ni tiwọn, ṣugbọn awọn arijagba ti wọn ti gbe orukọ ileewe wọn jade lati yaa bẹrẹ oludẹ tiwọn bayii, ko ma tun di pe wahala ni wọn yoo fi asiko ti wọn ba wa nileewe fa lẹẹkan si i.