Faith Adebọla, Eko
Adajọ Oluwatoyin Taiwo tile-ẹjọ akanṣe to wa n’Ikẹja ti sọ pe ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kejila, loun maa gbe idajọ kalẹ lori awijare olujẹjọ nipa awọn akọsilẹ ijẹwọ ti wọn ni Ọgbẹni Ọlanrewaju James Omiyinka tawọn eeyan mọ si Baba Ijẹṣa, ṣe lagọọ ọlọpaa ni Yaba.
Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ keji, oṣu kejila yii, ni igbẹjọ tun waye lori ẹsun fifipa ba ọmọde lo pọ, fifọwọ pa ọmọde lara lai yẹ, ati awọn ẹsun mi-in ti wọn fi kan gbajugbaja adẹrin-in poṣonu onitiata naa.
Nnkan bii aago mẹsan-an aabọ owurọ ni ẹlẹrii pataki to ta ko afurasi ọdaran naa, Abilekọ Damilọla Adekọya, tawọn eeyan mọ si Princess, wọle sinu yara igbẹjọ ọhun, ṣugbọn niṣe ni wọn sun igbẹjọ Baba Ijẹṣa si aago mejila, latari pe olujẹjọ naa ko si larọọwọto nigba ti Akọwe kootu pe orukọ ati ẹjọ rẹ.
Baba Ijẹṣa de laago mọkanla kọja iṣẹju mejila, wọn pe orukọ rẹ, kia lo ti kọja sinu akolo olujẹjọ to wa lapa osi adajọ, igbẹjọ si bẹrẹ lori ẹjọ naa.
Amofin agba Dada Awoṣika to ṣaaju awọn lọọya mẹrin mi-in lati gbeja olujẹjọ lo kọkọ sọrọ, o ni oun fẹ kile-ẹjọ wọgi le akọsilẹ ijẹwọ kan ti olujẹjọ sọ pe Baba Ijẹṣa kọ nigba to wa lahaamọ awọn ọlọpaa ni Yaba.
Awoṣika ṣalaye pe ojuṣe ẹni to kọwe ni lati fi ẹri ti gbe iwe to kọ lẹyin, ṣugbọn yoo ṣoro fun onibaara oun lati sọrọ lori iwe ti wọn kọ fun un, ti wọn si fipa mu un lati buwọ lu u.
Adajọ bi Awoṣika leere ohun to fẹ gan-an, agbẹjọro naa si fesi pe oun rọ ile-ẹjọ naa lati da awọn akọsilẹ tawọn olupẹjọ mu wa nu bii omi iṣanwọ, nibi ti wọn ti ni onibaara oun jẹwọ pe oun jẹbi ẹsun iwa palapala ti wọn fi kan an.
“Oluwa mi, bawo ni ile-ẹjọ ṣe le gbọkan le iru akọsilẹ ti wọn ni onibaara mi kọ, nigba ti wọn ti fiya jẹ ẹ, wọn lu u bii aṣọ ofi, wọn fi ankọọfu si i lọwọ, wọn wọ ọ nilẹ tuuru, ilẹẹlẹ lasan lo ni wọn da oun jokoo si bii aja, ti wọn fi ni koun buwọ lu akọsilẹ ti wọn lọọ kọ lorukọ ẹ ni kọrọ, ti wọn si fipa mu un pe ko gba pe ero oun lawọn kọ?
Ẹri wa niwaju ile-ẹjọ yii pe wọn fẹẹ fipa ti ọran mọ olujẹjọ lọrun ni, eyi si ta ko isọri kọkandinlọgbọn, abala karun-un, iwe ofin igbẹjọ. Ko si ẹri awuruju to kọja iyẹn, mo si rọ ile-ẹjọ lati gba a danu, ẹri apapandodo ni,” Awoṣika lo n bẹbẹ bẹẹ.
Amọ agbẹjọro olupẹjọ, Ọgbẹni T. E. Onilado dide, o si ta ko ẹbẹ olujẹjọ. O ni bo tilẹ jẹ pe ifiyajẹni waye nile Princess nigba ti wọn mu Baba Ijẹṣa, tawọn bọisi kan si ṣakọlu si i, o ni ko sẹni to fiya jẹ olujẹjọ naa ni teṣan ọlọpaa nigba ti wọn fi n gba akọsilẹ iwa to hu ọhun silẹ lẹnu rẹ, wọn o si fipa mu un lati buwọ luwe.
Onilado ni awawi lasan ni ọrọ agbẹjọro olujẹjọ, ati pe niṣe lo fẹ mọ-ọn-mọ ṣi ile-ẹjọ lọna, o si fẹẹ yii idajọ ododo po ni, tori ninu akọsilẹ kan, o darukọ ilu Badagry, nigba ti ko si ohunkohun to kan ilu Badagry ninu ẹjọ yii.
Lẹyin awijare tọtun-tosi, Adajọ Oluwatoyin ni iwe ibeere kan wa lọwọ oun, eyi tawọn olupẹjọ fi rọ ile-ẹjọ lati jẹ kawọn tun mu ẹlẹrii kan wa si i, ti yoo ta ko Baba Ijẹṣa.
Ṣugbọn agbẹjọro naa sọ pe ẹlẹrii ọhun taku, ko fẹẹ wa.
Eyi lo mu ki Adajọ Oluwatoyin paṣẹ pe ki wọn lọọ fun ẹlẹrii naa ni iwe aṣẹ ‘ile-ẹjọ fẹẹ ri ọ,’ ki ẹlẹrii naa si yọju sile-ẹjọ ni igbẹjọ to n bọ, ni ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kejila yii.
Bakan naa ni adajọ sọ pe ọjọ naa loun yoo pinnu boya kile-ẹjọ gba ẹri akọsilẹ ti wọn ni Baba Ijẹṣa kọ lagọọ ọlọpaa Yaba wọle, tabi ki wọn fa a ya.