Faith Adebọla
Ile-ẹjọ giga apapọ kan to fikalẹ siluu Abuja ti paṣẹ pe kileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ apapọ, iyẹn DSS (Department of State Security) lọọ san miliọnu meji naira (N2 million) owo itanran fun gbajugbaja ajafẹtọọ ati ajijangbara nni, Ọmọyẹlẹ Ṣoworẹ, latari bi wọn ṣe jẹbi gbigba ti wọn fipa gba foonu rẹ lasiko iwọde wọọrọwọ kan.
Adajọ Anwuli Chikere lo gbe idajọ naa kalẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii. Ninu idajọ rẹ lori ẹjọ ti Ṣoworẹ pe ta ko iwa aidaa ti DSS hu si i.
Agbẹjọro Ṣoworẹ, Abilekọ Funmi Falana, ṣalaye pe ọjọ kẹta, oṣu kẹsan-an, ọdun 2019, lawọn ẹṣọ ileeṣẹ DSS ya bo otẹẹli kan ti Ṣoworẹ wa, iyẹn si jẹ lalẹ to ṣaaju iwọde ‘Revolution Now’ ti Ṣoworẹ ṣagbatẹru ẹ ta ko ijọba apapọ, wọn fipa gba foonu iPhone olowo iyebiye rẹ, wọn tun ko ẹgbẹrun mẹwaa naira (N10,000) ninu yara to wa, ki wọn too fẹsun kan an pe iwọde rẹ ko bofin mu, wọn ni ọta ilu ni, pe o fẹẹ doju ijọba de ni.
O ni latigba naa ni Ṣoworẹ ko ti foju kan foonu rẹ ati owo naa, nigba tawọn si beere, wọn ni foonu naa ti ba jẹ, eyi lo mu ki wọn wọ wọn lọọ ile-ẹjọ tori iwa tawọn DSS hu naa tẹ ẹtọ Ṣoworẹ mọlẹ.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ Chikere bẹnu atẹ lu iwa tawọn DSS hu, o ni ko tọna bi wọn ṣe fipa gba foonu Ṣoworẹ, ti wọn si tun ko owo rẹ, o lo ta ko ẹtọ ọmọniyan to wa ninu iwe ofin ilẹ wa.
O lo yẹ ki awọn DSS kọkọ gba aṣẹ ile-ẹjọ na, ki wọn too ṣakọlu si ẹnikẹni, ile-ẹjọ nikan lo si le paṣẹ pe ki wọn gbẹsẹ le dukia ẹnikẹni. O ni ko si awijare kankan ti DSS ṣe to ba ofin mu, ati pe ọrọ rirun lo jẹ leti oun bi wọn ṣe sọ pe awọn ṣi n ṣayẹwo si foonu naa lati ọdun 2019 sasiko yii, tori awọn fẹẹ mọ boya loootọ ni Ṣoworẹ n ṣagbatẹru awọn afẹmiṣofo ati awọn ti wọn n doju ijọba de, o niwa buruku ni wọn hu.
Adajọ naa paṣẹ pe ki awọn DSS tọrọ aforiji lọwọ Ṣoworẹ, ki wọn kede aforiji naa sinu awọn iweeroyin ojoojumọ meji, ko si gbọdọ jẹ iweeroyin ṣakala kan o, awọn ti ipinkiri wọn kari Naijiria ni.
Lẹyin naa ni ki wọn san owo itanran miliọnu meji naira fun ẹni ti wọn fẹtọ rẹ du u.
Agbẹjọro Ṣoworẹ ni idajọ naa ba ododo mu, o si fihan pe ẹtọ ọmọniyan ṣi ṣee gbeja rẹ ni Naijiria.