Faith Adebọla, Eko
Ileewe girama Babs Fafunwa Millenium School, ti wọn n pe ni Ojodu Grammar School tẹlẹ, ti di titi pa bayii, ijọba Eko lo paṣẹ bẹẹ.
Kọmiṣanna feto ẹkọ, Abilekọ Fọlaṣade Adefisayọ, lo kede ipinnu Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, lori ileewe ọhun, lasiko to ṣabẹwo sibẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.
Ṣe, lọsan-an ọjọ Tusidee to ṣaaju abẹwo yii ni ijamba ọkọ kan waye lọna Ogunnusi, l’Ojodu, niwaju geeti ileewe naa, ọkọ akẹru kan to n ba ere buruku kọja ni nnkan bii aago meji aabọ ọsan tawọn ọmọleewe n sọda titi lati maa lọ sile wọn, kọ lu awọn ọmọ naa, o si pa bii mẹẹẹdogun lara wọn loju ẹsẹ, awọn bii mẹfa ti wọn fara pa yannayanna ṣi n gba itọju lọwọ lawọn ọsibitu bii mẹta kan lagbegbe naa.
Iṣẹlẹ ibanujẹ yii da wahala silẹ loju-ẹsẹ latari bawọn akẹkọọ yooku ṣe ya bo titi marosẹ naa, wọn n fibinu fọ gilaasi mọto akẹru ati tirela eyikeyii ti wọn ba ri ọgọọrọ awọn ọkọ ajagbe to rin sasiko naa lo fara kaaṣa ibinu awọn ọdọ.
Ọkọ to da wahala naa silẹ sa lọ, ṣugbọn awọn kan gba fi ya a, wọn si le e mu, bo tilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa ti sare de ibi iṣẹlẹ naa, ti wọn ko si jẹ kawọn ọdọ ribi ṣe dẹrẹba naa leṣe, wọn mu un lọ sakolo wọn.
Sibẹ, awọn ọmọleewe dana sun ọkọ ti wọn lo ko ọṣẹ ṣeyin rẹ ọhun, wọn si tun dana sun awọn ọkọ ajagbe mi-in pẹlu.
Bakan naa ni wọn fọ gilaasi ọkọ awọn ẹṣọ VIO (Vehicle Inspection Service) to n yẹ iwe ọkọ wo, wọn fẹsun kan wọn pe awọn ni dẹrẹba ọkọ akẹru naa n gbiyanju lati sa mọ lọwọ to fi ki ere asapajude mọlẹ, ti eyi si ṣokunfa ijamba naa, wọn ni niṣe lawọn VIO n le ọkọ naa bọ ṣaaju ijamba ọhun ni.
Yanpọnyanrin tiṣẹlẹ yii da silẹ lo mu kawọn ọlọpaa bẹrẹ si i yinbọn soke lati fi tu awọn ọdọ naa ka, nigba to si jọ pe ẹkọ ko fẹẹ ṣoju mimu lọjọ naa, wọn bẹrẹ si i yin afẹfẹ tajutaju (tear-gas) lu wọn, ti eyi si dẹrọ wahala diẹ, titi tilẹ ọjọ naa fi ṣu.
Ṣugbọn bilẹ ọjọ keji, Wẹsidee ṣe n mọ lawọn obi ati mọlẹbi ti ọmọ wọn fara gba ninu iṣẹlẹ naa ya bo ọgba ileewe naa, ti wọn bẹrẹ ifẹhonu han, wọn lo yẹ kijọba ti ti ileewe naa pa latari iṣẹlẹ yii, bẹẹ lawọn obi mi-in n wa awọn ọmọ wọn lati mu wọn kuro nileewe, o jọ pe wọn ti fura pe omi ijangbọn mi-in ti fẹẹ ho.
Bo tilẹ jẹ pe awọn agbofinro ko kuro lagbegbe naa lati dẹrọ wahala, niṣe lawọn ọdọ naa ya de lojiji, wọn tun bẹrẹ si i ṣakọlu sawọn onimọto, bẹẹ lawọn ọlọpaa n yin tajutaju si wọn lati le wọn, ṣugbọn bi wọn ṣe n sa nibi kan ni wọn n yọ nibomi-in. Bẹẹ asiko ti idanwo n lọ lọwọ lawọn ileewe kaakiri ipinlẹ Eko ni, awọn akẹkọọ naa ṣi n kọ idanwo lọwọ ki wahala yii to ṣẹlẹ.
Bi eyi ti n lọ lọwọ ni Kọmiṣanna Adefisayọ de pẹlu ikọ rẹ lati ẹka eto ẹkọ.
Obinrin naa ba awọn obi kẹdun ikunlẹ abiyamọ, o daro pe iku airotẹlẹ ti ko yẹ ko waye lo pa awọn ọmọleewe naa, o si jiṣẹ ibanikẹdun gomina Eko ati aya rẹ.
O ni ijọba ti paṣẹ pe ki ilẹkun yii ṣi wa ni titi pinpin na, ki igbokegbo eto ẹkọ ati idanwo to n lọ lọwọ si duro titi di oṣu ki-in-ni, ọdun 2022, tabi asiko mi-in ti ijọba ba kede.
Lẹyin to kuro nileewe naa lo lọọ ṣabẹwo sawọn ọmọ ti wọn wa nileewosan, nibi ti wọn ti n gba itọju lọwọ.
Ko pẹ ti iṣẹlẹ yii waye ni Ọga agba ẹṣọ oju popo, FRSC, ti wọn n pe ni Road Safety, Kọmanda Oluṣẹgun Ogungbemide, ti kede ninu atẹjade kan lọjọ Iṣẹgun pe awọn kọ lawọn le onimọto to ṣokunfa iṣẹlẹ yii, awọn o si mọ nnkan kan nipa ẹ rara, ṣugbọn gẹgẹ bii apa kan iṣẹ awọn, o di dandan kawọn ṣaajo awọn eeyan to ba fara kaaṣa ninu ijamba ọkọ bii eyi, lati doola ẹmi wọn, tabi ki wọn ko oku wọn ati awoku ọkọ kuro loju popo ki eyi ma tun lọọ ṣokunfa ijamba ati inira mi-in fawọn araalu.
Alukoro ileeṣẹ FRSC, Abilekọ Ọlabisi Ṣonusi sọ pe meje lara awọn ti wọn wa ni ẹsẹ-kan-aye ẹsẹ kan ọrun lawọn fi ọkọ awọn ko loju-ẹsẹ nibi ijamba naa, lẹyin naa lọkunrin alaaanu kan ko awọn meje mi-in wa si ibudo itọju pajawiri ti wọn ko wọn lọ.
Bakan naa ni Ọga agba ajọ to n ri lilọ bibọ ọkọ l’Ekoo, iyẹn LASTMA (Lagos State Traffic Management Authority), Ọgbẹni Bọlaji Ọrẹagba, ṣalaye pe ki i ṣe awọn oṣiṣẹ ajọ naa lo n le ọkọ akẹru to fa ijamba yii, wọn ni irọ lawọn to n darukọ ajọ LASTMA ninu iṣẹlẹ yii n pa mọ awọn.
Atẹjade ti ajọ naa fi lede l’Ọjọruu, Wẹsidee, ka lapa kan pe:
“Awọn iwadii ta a ṣe ati awọn iroyin ta a ri gba nibi tiṣẹlẹ yii ti waye fihan pe niṣe ni ọkọ akẹru yii padanu ijanu rẹ lori ere, bireeki rẹ lo feeli, ẹru to si ko sẹyin ko jẹ ki dẹrẹba naa le ṣakoso ọkọ ọhun mọ. Ṣugbọn awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii to lọọrin, a rọ awọn araalu ki wọn ṣe suuru, kawọn ọlọpaa pari iwadii wọn, ka le mọ hulẹhulẹ ohun to ṣẹlẹ.
Awọn oṣiṣẹ LASTMA ki i gbegi dina nibikibi lagbegbe ti jamba yii ti waye, a o si ni ibudo idari ọkọ nibẹ. Koda, lasiko ti iṣẹlẹ yii waye, gbogbo awọn ẹṣọ wa lo ti wa lawọn ẹka ileeṣẹ wa kaakiri fun ipade ọsọọsẹ ta a maa n ṣe, kidaa awọn ẹṣọ to n dari lilọ bibọ ọkọ nikan ni wọn ṣi wa lẹnu iṣẹ, awọn eleyii o si le le onimọto kan debi ti tọhun yoo sare asapajude.”
Bo tilẹ jẹ pe iṣoro gidi ṣi wa fun lilọ bibọ ọkọ lagbegbe yii lasiko ti a fi n ko iroyin yii jọ, sibẹ, wamuwamu lawọn agbofinro duro pẹlu ọkọ akọtami wọn lẹgbẹẹ wọn, lati le bomi pana wahala eyikeyii to ba fẹẹ rufin.