Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Adajọ ile-ẹjọ giga kan to wa ni Ado-Ekiti ti paṣẹ pe ki ọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlogbọn kan, Awoyẹlu Rotimi, maa lọ si ọgba ẹwọn titi di igba kan na.
Rotimi ti gbogbo eeyan mọ si (Bingo) too jẹ olukọ nileewe alakọọbẹrẹ kan ni Ado-Ekiti ni Onidaajọ Saka Afunṣọ paṣẹ pe ko lọọ maa gbatẹgun lọgba ẹwọn titi digba ti imọran yoo fi jade lati ọdọ ijọba.
Adajọ naa sọ pe oun paṣẹ naa nitori agbeyẹwo kan ti aṣoju agbefọba agba ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Felix Awoniyi, gbe wa si ile-ẹjọ naa ati pe oun ri i gẹgẹ bii oun to wulo ati to jẹ pataki ki ẹjọ naa too tẹ siwaju.
Rotimi ni wọn sọ pe o ṣe ẹsẹ naa niluu Ẹrinjiyan-Ekiti lasiko idibo ijọba ibilẹ to ṣẹṣẹ waye nipinlẹ Ekiti pẹlu bo ṣe ja apoti idibo gba lọwọ awọn oṣiṣẹ eleto idibo, to si dana sun un.
Wọn tun fẹsun biba dukia ijọba jẹ kan an pẹlu bo ṣe dana sun oun eelo fun eto idibo naa. Ẹsun yii ni ile-ẹjọ juwe gẹgẹ bii ohun to lodi sofin, to si ni ijiya labẹ ofin.
Ọkan lara awọn oṣiṣẹ eleto idibo naa to jẹrii nile- ẹjọ sọ pe ọdaran naa de ibi eto idibo naa ni deede agogo mẹsan-an aaro ọjọ ọhun pẹlu awọn janduku, to si gba gbogbo oun eelo fun idibo lẹyin igba to le awọn oṣiṣẹ eleto idibo naa ati awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu to wa niibi eto idibo naa.