Lọjọ Sannde to kọja yii ni iṣẹlẹ aburu kan waye nibi kan ti wọn n pe ni Vaijapur, lorilẹ-ede India. Ọmọkunrin kan tọjọ ori ẹ ko ju mẹtadinlogun lọ loun ati iya rẹ lọ sile ẹgbọn ọmọkunrin yii to jẹ obinrin (iya yii kan naa lo bi wọn).
Bi wọn ti debẹ tiyẹn ni koun lọọ ṣe tii fun wọn ki wọn mu ni aburo rẹ ki i mọlẹ, to si fi ada bẹ ọrun rẹ. Koda, iya wọn ni wọn lo di ẹsẹ ọmọbinrin naa mu lasiko ti eyi ọkunrin n dumbu ẹ, wọn si ṣe bẹẹ pa a pẹlu oyun oṣu meji ninu.
Ẹka iroyin Gatekeepers to fiṣẹlẹ naa sita ṣalaye pe Kirti Thore lorukọ ọmọbinrin ti aburo ati iya rẹ pa yii, ẹni ọdun mọkandinlogun (19) ni wọn pe.
Ẹṣẹ ti wọn lo ṣẹ wọn ko ju pe o n fẹ ọkunrin kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Avinash Thore, iya rẹ yii ko si fọwọ si i. Aburo to dumbu ẹ yii naa loun ko fẹran ẹni ti ẹgbọn oun fẹ ọhun, awọn si ba a sọ ọ titi pe ko ma fẹ ẹ, ko dahun.
Ifẹ ti wọ ọmọbinrin yii lọkan to bẹẹ lo ṣe lọọ loyun fun Avinash ti wọn ni ko gbọdọ fẹ, nigba to si ti loyun naa lo ti dọgbọn sa kuro nile, o sa gba ọdọ ẹni to fun un loyun lọ.
Nibẹ naa ni iya ati aburo ẹ wa a lọ lọjọ Sannde to kọja yii, ti wọn ni awọn waa ki i pe o ku ọjọ mẹta kan ni.
Inu Kirti dun lati ri iya ati aburọ rẹ, o yọ mọ wọn, o si wọ ile idana lọ lati lọọ ba wọn ṣe tii ti wọn yoo mu.
Tii ọhun lo n ṣe lọwọ ti aburo ẹ fi fada bẹ ẹ lori, ti iya rẹ di i lẹsẹ mu titi ti aburo ẹ fi ge ori naa kuro lọrun rẹ. Koda, nigba ti wọn ge ori ọhun tan, wọn gbe e dani ti wọn tun ba a ya fọto ti wọn n pe ni ‘selfie’ wọn lawọn reyin alaigbọran ọmọ.
Ọkọ ọmọ ti wọn pa yii wa nile, ṣugbọn wọn ni ara rẹ ko ya, idibulẹ aisan to wa ko jẹ ko le ṣe nnkan kan. Awọn to pa a ko si tilẹ fi bo pe awọn lawọn ṣiṣẹ naa, funra wọn ni wọn gba teṣan ọlọpaa Virgoan lọ, ti wọn lọọ fi ara wọn han nibẹ, wọn si jẹwọ pe awọn ṣẹṣẹ pa alaigbọran inu ile awọn tan ni.
Kailash Prajapati, ọlọpaa to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, sọ pe iya atọmọ apaayan yii ti wa lahaamọ, wọn yoo si jẹjọ ipaniyan laipẹ rara.