Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Latigba ti Ibrahim Chatta, gbajumọ oṣere tiata ti ni inu oun ko dun, oun ni ibanujẹ ọkan, lawọn ololufẹ rẹ ko ti jẹ ko gbadun pẹlu ipe.
Awọn kan tiẹ ti n sọ pe oṣere naa loun fẹẹ pa ara oun. Eyi lo mu Chatta yaa sare ju fidio kan sori ẹka Instagraamu to ti kede ibanujẹ ọkan lakọọkọ, o ṣalaye fawọn ti wọn ni o fẹẹ para ẹ pe ko sohun to jọ bẹẹ o.
Ninu fidio ti ọkunrin naa ṣẹṣẹ ju sori ayelujara naa lo ti dupẹ lọwọ awọn eeyan to pe e lori foonu, awọn to fi atẹjiṣẹ ranṣẹ atawọn ti wọn ṣi n pe titi dasiko yii.
O ni ifẹ ti wọn fi n han soun yii kun oun loju pupọ, o si ti jẹ ki ara oun ya gaga gidi, oun si gba pe eeyan laṣọ eeyan.
Lori ohun to fa ẹdun ọkan ati irẹwẹsi naa fun un, Chatta ni ko ju ti ẹṣin oun to ku lọ. O ni ẹṣin funfun ti owo rẹ wọn pupọ, to jẹ oun n tọju rẹ labule fiimu toun kọ, lo fo ṣanlẹ to ku lojiji.
Ibrahim loun fẹran awọn nnkan ọsin pupọ, paapaa ju lọ, ẹṣin. O ni wọn pọ toun ni lọwọ bẹẹ, ṣugbọn eyi to ku lojiji naa mu ọkan oun gbọgbẹ pupọ, oun fẹran rẹ pupọ, iku rẹ si da bii ọfọ ati ibanujẹ ọkan nla foun. O ni ohun to mu ọkan oun rẹwẹsi toun ko si le ṣe nnkan kan niyẹn.
Oṣere yii sọ ọ di mimọ pe bawọn eeyan ṣe waa n pe oun kaakiri agbaye, toun ko le gbe e nitori ibanujẹ naa, toun ko si le pe pada ki i ṣe ti afojudi, ko si ki i ṣe pe oun n dan wọn wo lati mọ boya wọn nifẹẹ oun, o loun mọ pe awọn eeyan fẹran oun daku, oun naa si nifẹẹ wọn gidi.
Fun awọn ti wọn ṣeto lori ayelujara ti wọn sọ pe oun fẹẹ para oun, Chatta ni, “Awusubilahi minaṣaitọọni rọjeem. Mi o sọ pe mo fẹẹ para mi o, mi o tiẹ ronu iru ẹ, Ọlọrun o ni i jẹ ka ri iru iyẹn”
Bo ti n ṣe fidio ọhun lawọn eeyan tun un pe e, oun naa si n fi idunnu rẹ han, o loun ko ronu mọ, boun ṣe n mura ni yara otẹẹli toun ti n ṣe fidio yii, oun n lọ sibi afihan sinima kan ni. Inu oun ti n dun, oun ko ronu mọ.
Oṣere naa loun ko ni i ku bayii, awọn ololufẹ oun naa ko ni i rọrun ojiji, wọn o si ni i ṣọfọ tọmọtọmọ.