Ọlawale Ajao, Ibadan
Pẹlu bi ọdun Keresi ṣe wọle de tan, tọdun tuntun si n kanlẹkun gbọngbọn, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti ṣilẹkun ahamọ wọn silẹ gbayau fanfaani awọn ti ko ba bikita lati ṣe eyikeyii ninu awọn ọdun naa latimọle.
Ọga agba ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Ngozi Onadeko, lo paṣamọ ọrọ yii nigba to n kede ijiya fawọn to fẹran lati maa yin banga lasiko pọpọṣinṣin ọdun Keresi atọdun tuntun.
Bakan naa lobinrin olori awọn agbofinro yii fofin de ajọdun adugbo ti wọn n pe ni kanifa nibikibi ni ipinlẹ yii.
Ninu atẹjade to fi ṣọwọ sawọn oniroyin laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, nipasẹ DSP Adewale Oṣifẹṣọ ti i ṣe alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, CP Onadeko sọ pe latoni lọ, o ti deewọ fẹnikẹni lati yin banga.
Bakan naa lo fofin de okoowo banga fawọn alatẹ, o ni ijiya to wa fawọn to ba yin banga naa lo wa fawọn to n ta a nitori atẹni to ba yin in, ati oniṣowo ti wọn ba ba kinni ọhun nigba ẹ, inu atimọle ni gbogbo wọn n lọ.
O waa rọ awọn obi lati kọwọ ọmọ wọn bọṣọ. Bẹẹ lo kilọ fawọn ọdọ paapaa lati so ewe agbejẹẹ mọwọ bi wọn ko ba fẹẹ ṣọdun to n bọ latimọle.
Lati fi han gbogbo araalu pe awọn ikilọ yii ki i ṣe ọrọ ẹnu lasan, CP Onadeko ti paṣẹ fawọn ọga ọlọpaa lagbegbe kọọkan kakairi ipinlẹ naa lati maa wa awọn arufin naa kiri, ki oun le fiya to ba tọ jẹ wọn labẹ ofin.