Ọlawale Ajao, Ibadan
Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ti ṣapejuwe ipapoda Aṣigangan tilu Igangan, Ọba Abdul Azeez Adewuyi (Aribiyan Keji), gẹgẹ bii adanu mi-in fun ilu Igangan ati gbogbo ipinlẹ Ọyọ lapapọ.
Nirọlẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni Makinde sọrọ naa nipasẹ atẹjade latọwọ Ọgbẹni Taiwo Adisa ti i ṣe akọweeroyin rẹ.
Ta o ba gbagbe, laaarọ ọjọ Tusidee, ọsẹ yii l’Aṣigangan tilu Igangan waja lẹyin ọjọ mẹsan-an ti Ṣọun tilẹ Ogbomọṣọ, Ọba Jimọh Oyewumi (Ajagungbade Kẹta), wọ kaa ilẹ lọ.
Gomina Makinde, ẹni to fi ẹdun ọkan ẹ han nipa ipapoda ọba naa ninu atẹjade ọhun ṣalaye pe “Aṣigangan to waja yii jẹ adari to nifẹẹ alaafia ati idagbasoke ilu ẹ.
“Lori gbogbo igbesẹ ti ijọba ba n gbe lati mu ki alaafia jọba niluu Igangan ni Kabiesi maa n fọwọsowọpọ pẹlu wa.”
O waa ba idile ọba naa, awọn ara Igangan ati ipinlẹ Ọyọ lapapọ kẹdun ipapoda ọba to waja yii.