Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ileeṣẹ ọlọpaa ẹka ti ipinlẹ Kwara ti mu awọn afurasi adigunjale mẹta yii, Adebayọ Akeem, ẹni ogoji ọdun, Akintọla Abdullahi, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, Muyiwa Obaseki, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn, ti wọn wa lati ilu Ibadan, ti wọn si n ja awọn ero Takisi lole niluu Ilọrin.
Ninu atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, fi sita to tẹ ALAROYE, lọwọ niluu Ilọrin, ni Ọjọruu, Wẹsideee, ọṣẹ yii, lo ti ṣalaye pe ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni iroyin tẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara lọwọ pe awọn afurasi adigunjale kan n fi mọto Takisi ja awọn eniyan lole ti wọn si ti ja Arabinrin Ọmọedemi Ayoleyi, lole ẹgbẹrun lọna mejidinlogoji Naira ati yẹti oni goolu ti ko din ni aadọta Naira lagbegbe Otẹẹli kan niluu Ilọrin.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ naa, CP Tuesday Assayomo, ti paṣẹ ki wọn dọdẹ awọn ole ọhun, ki wọn si fi wọn jofin, SP Ajayi Okasanmi tẹsiwaju pe pe ọwọ pada tẹ awọn afurasi ọhun, ti wọn wọn si ti n ṣẹju peu lakolo ọlọpaa bayii.
CP Tuesday Assayomo ti ni ki wọn ṣe ẹkunrẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa, o tun rọ awọn olugbe ipinlẹ Kwara lati tete maa kan si agbofinro nigbakuugba ti wọn ba kẹẹfin iwa ọdaran tabi ohun ajeji lagbegbe wọn.