Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti tẹ ọkunrin ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn kan, Ayọdele Bankọle, ẹni ti wọn fẹsun kan pe o gun ọrẹbinrin rẹ pa sinu otẹẹli kan l’Akurẹ.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Oyeyẹmi Oyediran, lo fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fawọn oniroyin lasiko to n ṣafihan afurasi ọdaran ọhun lolu ileeṣẹ wọn to wa loju ọna Igbatoro, Alagbaka, niluu Akurẹ, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.
Oyediran ni ṣe ni Bankọle gbe ọmọbinrin ẹni ọdun mẹrinlelogun naa lọ sile-itura kan ti wọn n pe ni Enjoy Your Life, niluu Akurẹ, nibi to gun un lọbẹ pa si, to si fẹẹ maa sa lọ.
O ni awọn oṣiṣẹ ileetura naa ni wọn ri Bankọle to bẹrẹ si i sa lọ lẹyin to ti bẹ silẹ lati ori atẹgun ti wọn fi n goke ile pẹtẹẹsi ọhun.
Kiakia lawọn eeyan to wa nitosi ti tẹle e, wọn si le e titi ti wọn fi ri i mu, lẹyin naa ni wọn wọ ọ pada sinu yara otẹẹli to ti sa kuro bẹẹ, nibi ti wọn ti ba ọmọbinrin ta a n sọrọ rẹ yii to n japoro iku ninu agbara ẹjẹ pẹlu oju ọgbẹ ọbẹ lọrun ati aya rẹ.
Awọn eeyan ọhun lo sare gbe ọmọbinrin naa lọ sileewosan, nibi tawọn dokita ti fidi rẹ mulẹ pe o ti ku.
Nigba tawọn oniroyin n fọrọ wa afurasi ọhun lẹnu wo lori ẹsun ti wọn fi kan an, ṣe lo ṣẹ kanlẹ patapata, o ni irọ ni gbogbo rẹ.
O ni ọlọkada loun, ati pe alejo kan ti oun gbe lọ si otẹẹli ọhun loun n duro de ti wọn fi waa mu oun pe oun paayan.
Oyediran ti ni afurasi ọhun ko ni i pẹẹ foju bale-ẹjọ lẹyin ti iwadii ba ti pari lori ẹsun ti wọn fi kan an.
Bankọle gun ọrẹbinrin rẹ pa ninu otẹẹli l’Akurẹ