Eyi nidi ta a fi tun ko awọn onibaara kuro loju titi n’Ibadan-Ọlayiwọla

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ijọba ipinlẹ Ọyọ, labẹ iṣakoso Gomina Ṣeyi Makinde, ti tun palẹ awọn to n tọrọ baara mọ kuro lẹgbẹẹgbẹẹ titi gbogbo nigboro Ibadan.

Kọmiṣanna fọrọ awọn obinrin ati eto igbaye-gbadun araalu nipinlẹ naa, Alhaja Kafilat Ọlayiwọla, lo ko awọn agbofinro sodi lọọ ṣiṣẹ naa lọjọ kẹtalelogun (23), oṣu kejila, ọdun 2021 yii.

Lara awọn adugbo ti wọn ti ṣiṣẹ ọhun ni Ikorita Mọkọla, Ojuna Jẹmibẹwọn, Sango, Ikorita Ọjọọ Roundabout, Ẹlẹyẹle, Challenge, Iwo Road, Gbagi, Mọnatan ati Dugbẹ.

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ lẹyin eto naa, Alhaja Ọlayiwọla sọ pe ni kete ti oun dori aleefa gẹgẹ bii kọmiṣanna loun ti lọọ ṣabẹwo sawọn agbegbe ti awọn to n tọrọ baara fi ṣebugbe lati sọ asọtẹlẹ fun wọn nipa igbesẹ ti oun ṣẹṣẹ gbe yii.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Ṣe ẹ mọ pe eyi kọ nigba akọkọ ti ijọba maa ko awọn onibaara kuro loju titi. A si mọ pe awọn iran Hausa ati Fulani lo pọ ju ninu awọn onibaara. Nigba ti mo ṣabẹwo sawọn aṣaaju wọn, inu tiwọn naa ko dun si bi awọn eeyan awọn ṣe tun pada sẹgbẹẹ titi lati maa ṣagbe lẹyin ti ijọba ti ko wọn kuro nibẹ ṣaaju.”

Obinrin yii waa ṣeleri pe loorekoore nijọba yoo maa gbe iru igbesẹ yii lati ṣafọmọ igboro Ibadan kuro ninu idọti ti awọn onibaara n da soju titi gbogbo.

Leave a Reply