Adefunkẹ Adebiyi
Awọn pasitọ agba meji ni Naijiria, Olori ijọ Irapada, Baba Enoch Adeboye ati Dokita Daniel Olukọya ti i ṣe Olori ijọ Mountain of Fire Ministries (MFM) ti gbe asọtẹlẹ tiwọn fọdun tuntun 2022 yii jade, wọnyi lawọn ohun ti wọn wi.
Pasitọ Adeboye sọ lọjọ kin-in-ni, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022, pe ọna mẹta ni aṣọtẹlẹ oun pin si. Akọkọ ni fun ẹda eeyan kọọkan, Naijiria gẹgẹ bii orilẹ-ede ni asọtẹlẹ keji wa fun, nigba ti ikẹta wa fun ilẹ okeere.
Fun ti ẹni kọọkan, Baba sọ pe pupọ ninu adawọle awọn eeyan ni yoo yọri si rere lọdun yii, koda yoo ju ida ọgọrin lọ, nitori ọdun ti ogo aimọtẹlẹ yoo bu jade ree.
Baba Adeboye sọ pe pẹlu gbogbo ohun to n ṣẹlẹ yii, ọdun ti ọna yoo la nipa imọ sayẹnsi ati eto inawo ree. Bẹẹ ni olori ijọ Ridiimu naa sọ pe iku ọmọde yoo dinku ni ida adọta, o kere ju.
Ni ti Naijiria,Pasitọ Adeboye sọ pe ẹni to fẹẹ joyin inu apata ko ni i wẹnu aake ni o. Wọn ni awọn nnkan kan yoo kọkọ nira kawọn eeyan le jẹ ọrọ to yẹ ki wọn jẹ.
Abala kẹta ti i ṣe ti ilẹ okeere ni Baba sọ pe yoo gba ọna mi-in yọ lọdun yii. Wọn ni eto irinajo lati orilẹ-ede kan si ibomi-in yoo yatọ si bi nnkan ṣe wa tẹlẹ.
Nigba to n gbe asọtẹlẹ tiẹ fọdun 2022 yii kalẹ, Olori ijọ MFM, Pasitọ Daniel Olukọya, ṣalaye pe iji abami meji yoo ja loju agbami. O ni ọkan yoo wa lati okun Atlantic, ikeji yoo si wa lati Pacific. O ni bi adura ko ba pọ, bi awọn iji yii ba fi ja, yoo le gan-an ni, ipalara rẹ yoo si pọ.
Bakan naa ni Olukọya ni kawọn ọmọ Naijiria gbadura nitori ìyaǹ, iyẹn aisi ounjẹ. Ki wọn gbadura lori aisowo niluu ati ki ọja maa wọn si i, ki wọn si tun gbadura ki oṣelu rẹsẹ duro, nitori ọpọ eeyan ni nnkan yoo daru mọ lọwọ nipa ọrọ awọn oloṣelu yii.
“A gbọdọ gbadura lati ṣẹgun awọn iku aimọdi, ijọ Ọlọrun nilo adura lori awọn to n gbogun ti awọn Kristẹni. Ọlọrun n ṣeto nnkan kan fun Naijiria, yoo si dahun adura awọn ọmọ rẹ.
“Gbogbo agbara to ba fẹ ki Naijiria wo lo maa wo, agbara to fẹ ki Naijiria ku lo maa ku, wọn yoo mu ẹjẹ ara wọn, wọn yoo si jẹ ẹran ara wọn titi ti wọn yoo fi yo kẹri ni.”
Bẹẹ ni Pasitọ Olukọya sọ asọtẹlẹ saye Naijiria.