Ọlawale Ajao, Ibadan
Bo tilẹ jẹ pe baba naa ti dagba, gbogbo eeyan ni ipapoda Olubadan tilẹ Ibadan, Ọba Saliu Akanmu Adetunji ba lojiji.
Laaarọ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ keji, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022, lọba naa dara pọ mọ awọn baba nla ẹ. Ileewosan ijọba apapọ, iyẹn University Teaching Hospital (UCH), n’Ibadan, lọba naa mi imi ikẹyin si lẹyin ọdun mẹfa pere to lo lori itẹ.
Iwadii akọroyin wa fìdi ẹ mulẹ pe o ti to bii ọjọ mẹta kan ti ailera to ni i ṣe pẹlu ogbo ti n pe ọba naa nija.
Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ti ṣapejuwe ipapoda ọba naa gẹgẹ bii iṣẹlẹ to ba oun paapaa lojii.
Ninu atẹjade ti Ọgbẹni Taiwo Adisa ti i ṣe akọwe iroyin rẹ fi ṣọwọ sawọn oniroyin lo ti ṣapejuwe Ọba Adetunji gẹgẹ bii akinkanju ọba to daabo bo aṣa ati iṣe Ibadan nigba aye ẹ, ti idagbasoke ilu naa ati ipinlẹ Ọjọ lapapọ si jẹ logun.
O waa ki idile ọba naa, gbogbo ọmọ ilẹ Ibadan ati ipinlẹ Ọyọ lapapọ ku aṣẹyinde ọba wọn to lọ.
Tẹ o ba gbagbe, lọjọ mọkanlelogun ṣaaju, iyẹn lọjọ kejila, oṣu kejila, ọdun 2021, ni Ṣọun Ogbomọṣọ, Ọba Jimọh Oyewumi, dagbere faye, ti Aṣigangan tilu Igangan, Ọba Abdul Azeez Adewuyi, si tẹle e lọjọ kẹwaa ti i ṣe ọjọ kọkanlelogun, oṣu naa.
Ẹni ọdun mẹtalelaaadọrun-un (93) l’Olubadan to waja laaarọ yii. Olori, ọpọ ọmọ ọmọọmọ ati ọmọ-ọmọ-ọmọ lo gbẹyin ọba ẹlẹyinju aanu naa, ẹni to fi odidi maaluu kan ta awọn oniroyin n’Ibadan lọrẹ lọsẹ to kọja.
Ni nnkan bii aago mẹrin irọlẹ yii ni wọn yoo sinku ọba naa nilana Musulumi.