Faith Adebọla
Aarẹ Muhammadu Buhari ti loun ni i sọ ẹni tọkan oun fẹ lati bọ sipo aarẹ lẹyin toun ba ti pari saa iṣakoso oun, o ni ọbẹ ki i mi nikun agba loun maa fi ọrọ naa ṣe, tori wọn le lọọ pa iru onitọhun danu toun ba darukọ ẹ.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu ileeṣẹ tẹlifiṣan Channels lalẹ Ọjọruu, Wẹsidee, lo ti sọrọ ọhun.
Nigba tawọn oniroyin bi i leere boya ẹnikan pato wa ti Aarẹ nifẹẹ si pe ko di aarẹ lẹyin rẹ, o fesi pe: “Rara, ẹ jẹ kẹnikẹni to ba n bọ maa bọ, ẹni yoowu ko jẹ ni.
“Ohun to ṣe koko ni pe ma a ri i akọsilẹ wa, tori mi o fẹ kẹnikan waa pe mi pe ki n waa jẹrii nile-ẹjọ. Aijẹ bẹẹ, onitọhun maa ko sijangbọn ni. Gbogbo nnkan to maa nilo lati mọ, aa ti wa lakọọlẹ, ma a ri i daju pe akọsilẹ yẹn wa, o si peye, gbogbo ọrọ to ṣe koko lo maa wa ninu ẹ.”
Wọn tun bi Buhari leere boya o ni ẹnikan pato lọkan ninu ẹgbẹ oṣelu rẹ, All Progressive Congress (APC), to maa fẹ ko bọ sipo aarẹ, o ni: “Rara o, mi o ni ẹnikan lọkan, mi o si le darukọ ẹnikẹni, tori wọn le lọọ pa tọhun danu. Ẹ jẹ ki n fi tọhun sikun ara mi, iyẹn lo daa ju.”
Bẹẹ ni Buhari wi.