Ọlọpaa ipinlẹ kọ lọrọ kan, mi o fara mọ ọn-Buhari

Faith Adebọla

Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣalaye pe oun ko fara mọ idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ tawọn eeyan n pariwo ẹ latọjọ yii, o ni ọrọ naa ko si ninu aba toun le gbe yẹwo rara.

Ọrọ yii wa lara ibeere tawọn oniroyin bi i lasiko ifọrọwanilẹnuwo ileeṣẹ tẹlifiṣan Channels to waye l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

Nigba ti wọn beere lọwọ Aarẹ Buhari boya o ti gba lati fara mọ idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ, ki eto aabo le tubọ lagbara si i, Buhari ni oun o fara mọ ọn rara, ni toun.

“Idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ ko tiẹ si ninu ọrọ rara, ko si ninu aba to yẹ keeyan mu wa, emi o fara mọ ọn.

“Ẹ lọọ beere bi nnkan ṣe ri laarin awọn ijọba ibilẹ ati awọn gomina ipinlẹ wọn gbogbo, ki wọn sọ ootọ fun yin nipa ajọṣe wọn.

“Njẹ ẹka ijọba kẹta yii (ijọba ibilẹ) n ri ẹtọ wọn gba gẹgẹ bi ofin ṣe la a kalẹ? Ẹ jẹ kawọn ijọba ibilẹ salaye fun yin, ki wọn sọ ootọ ibẹ fun yin, ija buruku lo n lọ laarin awọn ijọba ibilẹ atawọn gomina wọn.”

Ṣaaju asiko yii ni Buhari ti loun o fara mọ idasilẹ ọlọpaa ibilẹ, o ni aṣilo agbara maa gbilẹ ti wọn ba faaye gba awọn ipinlẹ lati ni ọlọpaa kaluku wọn.

Leave a Reply