Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtala, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022 yii, ni Aarẹ Muhammadu Buhari yoo ṣabẹwo sipinlẹ Ogun, lati waa ṣi awọn iṣẹ pataki ti Gomina Dapọ Abiọdun ti ṣe.
Atẹjade to wa lati ọfiisi Akọwe iroyin Gomina Dapọ Abiọdun, Ọgbẹni Kunle Ṣomọrin, ṣalaye pe gbagede Gateway City Gate Monument Park, eyi to wa ni Ṣagamu Interchange, ni wọn yoo ti ki Aarẹ kaabọ laago mẹwaa aarọ, nibi ti yoo ti ṣiṣẹ akọkọ.
Yatọ si gbagede yii, awọn iṣẹ mi-in ti wọn tun ni Buhari yoo ṣi ni oju ọna Ijẹbu-Ode Mọjọda-Ẹpẹ, ti i ṣe marosẹ. Ati ile akọgbe rẹpẹtẹ; ẹsteeti olowo pọọku to le ni ẹẹdẹgbẹta, to wa ni Kọbapẹ, atawọn towo rẹ ko pọ ti ko si kere ju, pẹlu awọn eyi to gbe pẹẹli diẹ ti wọn n pe ni Kings Court Estate, to wa l’Oke-Mosan, l’Abẹokuta.
Nipa awọn alejo to n bọ, atẹjade naa sọ pe aago mẹsan-an aabọ aarọ ni ki wọn ti wa nijokoo ni City Gate, Interchange, bẹẹ ni wọn yoo ni lati pa gbogbo ofin to de aisan Koro mọ.