Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Laipẹ yii ni Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, buwọ lu u pe awọn ẹbi ọba to ba waja lẹtọọ lati sin oku rẹ nilana ẹsin ti ọba ba n sin nigba to wa laye. Igbesẹ yii lodi sohun tawọn Oniṣẹṣẹ ti wọn n fi ọba jẹ fẹ, nitori wọn ko gba aba naa nigba to wa nileegbimọ aṣofin Ogun, wọn ni ohun ti ko kan ijọba ni wọn n da si.
Lati waa mọ ohun ti awọn oniṣẹṣe yoo ṣe lẹyin aṣẹ gomina, ALAROYE ba Ọba Ogboni Agba, Dokita John Daisi, to n gbe nipinlẹ Ogun, sọrọ lori iha ti wọn kọ si igbesẹ ijọba yii, baba naa ṣalaye pe, ‘‘Mo ti sọ fun wọn pe bi wọn ṣe sin Olubadan ati Ṣọun ko ba ilana mu rara, bẹẹ yẹn kọ ni wọn ṣe n sin ọba.
“Eyi ti gomina sọ nipinlẹ Ogun yii ni tiẹ, ẹyin ẹ maa woran, ijọba n tan ara ẹ ni. Ki i ṣe pe awa Oniṣẹṣe maa pe ẹjọ o, a o ni i pe wọn lẹjọ, ṣugbọn nigba ti wọn ba bẹrẹ si i ri ohun to n ṣẹlẹ, ibi ti wọn ba ku de, ẹnikan o ni i sọ fun wọn ki wọn too mọ pe o yẹ ki wọn ṣe ohun to yẹ ki wọn ṣe.
“Ṣe nigba iwaṣẹ, ṣe gomina lo n feeyan jọba? Kẹ ẹ fi mọ pe wọn n mọ-ọn-mọ ba Iṣẹṣe jẹ ni. Gomina kọ lo n feeyan jọba nigba iwaṣẹ, ẹ waa ni wọn o ni i maa ji ọba gbe kiri. Ọba ti wọn o ṣetutu, ti wọn o ṣe nnkan kan fun, oriṣiiriṣii iwọsi lo maa maa ba a nibẹ.”
O ti ṣe diẹ ti ọrọ bi wọn yoo ṣe maa sin ọba to ba waja, ati bi wọn yoo ṣe maa fi wọn jẹ ti wa nileegbimọ aṣofin Ogun. Wọn ti jokoo lori ẹ lọpọ igba, bẹẹ ni wọn ti ṣepade ita gbangba.
Awujalẹ ilẹ Ijẹbu, Ọba Sikiru Kayọde Adetọna, lo ṣagbatẹru ofin yii, eyi ti wọn fi n sọ pe ko sohun to daa bii ki wọn sin ọba Musulumi nilana ẹsin ẹ, ki wọn si sin ọba Kristẹni nilana awọn onigbagbọ.
Ṣugbọn eyi ko ri bẹẹ lọdọ awọn Oniṣẹṣe ti wọn n ṣoro ọba. Wọn ni gbogbo oro to n sọọyan dọba lọba gbọdọ ṣe ko too gori itẹ, to ba tun papoda pẹlu, o tun ni ohun tawọn yoo ṣe labala isinku, ẹni to ko ba si m’awo, ko le royin ohun to n ṣẹlẹ ni’ledi awo. Iyẹn ni wọn ṣe ni kijọba ma da si i rara.
Ṣugbọn Gomina Abiọdun ti sọ ọ dofin pe awọn ẹbi ọba lẹtọọ lati sin in nilana to ba ẹsin ọba mu, bo tilẹ jẹ pe oun ko ni ki wọn tapa sawọn Oniṣẹṣe patapata, nitori iṣẹṣe lagba, ṣugbọn o ni kawọn to n ṣoro yii fi awọn ẹbi oku silẹ, ki wọn sin eeyan wọn nilana ẹsin ẹ. Ati pe bi wọn yoo ba tiẹ yan ọba tuntun pẹlu, gbogbo ẹ gbọdọ gba ilana tuntun ti ko ruju, ti ko tẹ ẹtọ ẹni mọlẹ, ti ko si fipa mu’ni nibi kankan.
Ọrọ yii ṣi wa nilẹ bayii, bo tilẹ jẹ pe gomina ti paṣẹ tiẹ, ohun to daju ni pe ko dun m’awọn Oniṣẹṣe ninu.