Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ajọ ẹṣọ alaabo ṣifu difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ Kwara, ti mu afurasi kan, Victor Adebayọ, ẹni ọdun mẹrinlelogun, to n lu awọn oni POS ni jibiti niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, nipa ṣiṣe ayederu alaati fun wọn.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ to lọ yii, ni adari ajọ ẹṣọ naa ni Kwara, Ọgbẹni Makinde Ayinla, gba awọn to n ṣowo POS ni imọran lati maa ṣọra ṣe pẹlu awọn ayederu onibaara ti wọn aa fẹ gbowo, ti wọn yoo si maa ṣe ayederu alaati fun wọn. O tẹsiwaju pe lasiko ti awọn oṣiṣẹ ajọ naa n yide kiri lọwọ tẹ ọkunrin kan to n jẹ Victor Adebayọ, to maa n lu awọn oni POS ni jibiti nipa ṣiṣe ayederu alaati, to si ti lu awọn eniyan ni jibiti owo to le ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹjọ Naira.
Agbẹnusọ ẹsọ ọhun, Ọgbẹni Babawale Zaid Afolabi, sọ pe afurasi naa jẹwọ pe loootọ loun maa n lu awọn oni POS ni jibiti, ati pe ilu Eko loun n gbe, ti yoo si lọ sọdọ awọn oni POS, toun yoo gba owo lọwọ wọn, toun yoo si ṣe ayederu alaati, ti owo irọ yoo si dun.
Afọlabi ni ninu ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Corolla kan ni afurasi ọhun ti yoo dibọn bii ẹniyan gidi yoo jokoo si.
Ọkunrin naa jẹwọ pe o ti le ni ọdun meji toun ti n ṣiṣẹ buruku yii, ati pe igba miiran wa ti oun yoo dibọn bii pasitọ, ti oun yoo si sọ fun oni POS pe iyawo oun wa nileewosan, ti wọn si nilo owo, ko le rowo gba lọwọ ẹni to fẹẹ lu ni jibiti.