Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Awọn ẹgbẹ kan ti wọn n pe ara wọn ni ‘The Progressive Project’ , ( TPP) ti wọn n ṣatilẹyin fun Igbakeji Aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, lati di aarẹ lọdun to n bọ ti ni awọn lawọn yoo bori nibi idibo abẹlẹ ẹgbẹ APC.
Wọn lawọn yoo fi iwa ọmọluabi bori awọn afowo-ṣoṣelu ni.
Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹjila, oṣu kin-in-ni, ọdun tuntun yii, ni ọrọ yii jẹ jade niluu Abuja, iyẹn lẹyin ti wọn gbalejo awọn ẹgbẹ mẹtadinlọgọta ti wọn jẹ ọdọ.
Kaakiri lawọn ọdọ naa ti wa ni Naijiria, awọn akẹkọọ wa ninu wọn pẹlu, gbogbo wọn n ṣatilẹyin fun Ọṣinbajo lati di aarẹ ni 2023 ni.
Yatọ sawọn eyi, awọn alatilẹyin Ọṣinbajo ti wọn to ẹẹdẹgbẹta ( 500) kaakiri ipinlẹ Naijiria tun wa s’Abuja lọjọ naa, orin kan naa ti gbogbo wọn n kọ ni pe Yẹmi Ọṣinbajo lo le ṣe e.
Pẹlu ero rẹpẹtẹ yii lawọn TPP fi sọ pe awọn ti bẹrẹ eto oriṣiiriṣii ti yoo jẹ kawọn gbẹyẹ lọwọ awọn to n fowo ra ipo.
Wọn ni jijẹ ọmọluabi bii Ọjọgbọn Ọṣinbajo ti to lati bori ibo pamari lẹgbẹ APC, tawọn yoo si jẹ kawọn yooku mọ pe orukọ rere san ju wura ati fadaka lọ.
Olori ẹgbẹ TPP, Ọgbẹni Jeffrey Omoh, to ba awọn aṣoju ẹgbẹ kọọkan sọrọ, tẹnu mọ ọn pe ọna tawọn yoo gbe ipolongo tawọn gba yoo jẹ nipa yiyan awọn eeyan to nifẹẹ orilẹ-ede yii dọkan, awọn ko ni i fi naira kooyan jọ.
O rọ awọn to pejọ sibi ipade naa pe ki wọn pada sile, ki wọn foju inu wo agbegbe wọn wo daadaa, ki wọn ba awọn ara adugbo wọn rẹ si i, ki wọn si pada wa pẹlu awọn amọran ti yoo ṣẹgbẹ loore lati bori awọn alagbara ti yoo fẹẹ fowo fa oju awọn eeyan mọra.