Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ileeṣẹ ọlọpaa, ẹka ti ipinlẹ Kwara, ti wọ baba ẹni ogoji ọdun kan Alade Ọlasunkanmi, lọ siwaju ile-ẹjọ Magistreeti kan niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, fẹsun pe o sẹku pa baba rẹ ni Agboole Oke Apa, l’Omu-Aran, o si ju oku ẹ si gbo.
ALAROYE gbọ pe oku baba Ọlasunkanmi ni wọn ri leti igbo ni Oke Apa, niluu naa, ti wọn ti ge ọwọ osi rẹ.
Eyi lo mu ki wọn gbe oku naa lọ sileewosan Jẹnẹra tilu Omu-Aran fun ayẹwo finni-finni.
Nigbẹyin ni aṣiri tu pe Alade Ọlasunkanmi lo ṣeku pa baba rẹ lẹyin ti ede aiyede kekere kan bẹ si silẹ wọn laarin wọn, ti awọn mọlẹbi ko si ri i pari, eyi lo fa a ti wọn fi mu un.
Olupẹjọ, Olayide Sekunda, rawọ ẹbẹ sile-ẹjọ pe ko fi Ọlasunkanmi si ahamọ ni ọgba ẹwọn tori pe iwa ipaniyan ko ṣee fọwọ yẹpẹrẹ mu.
Onidaajọ Dajọ Fọlake Olokoyọ, to n gbọ ẹjọ rẹ ti paṣẹ pe ki wọn lọọ fi i si ahamọ titi di ọjọ keje, oṣu keji, ọdun yii, ti igbẹjọ miiran yoo waye.