Miliọnu marun-un lawọn agbebọn to ji Rahamon l’Omu-Aran n beere fun 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Awọn ajinigbe to ji Rahamọn gbe ninu ile rẹ niluu Omu-Aran, loru ọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii, ti n beere fun miliọnu marun-un naira owo itusilẹ lọwọ mọlẹbi rẹ.

Arabinrin Rasheedat Owoyẹmi to jẹ ọkan lara mọlẹbi to ba ALAROYE sọrọ sọ pe oru ọjọ Aiku, Sannde, mọju ọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii, ni awọn ajinigbe naa ya bo ile awọn Rahamọn, wọn ja ilẹkun mọ wọn lori, wọn ba iyawo ati ọkọ ninu ile, ni wọn ba ji ọkọ gbe sa lọ.

Ṣugbọn ni aago mejila oru mọju ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, ni awọn ajinigbe ọhun pe awọn mọlẹbi, ti wọn si ni ti wọn ba fẹẹ ri ọmọ wọn laaye, ki wọn tete fi miliọnu marun-un ṣọwọ kiakia, bi bẹẹ kọ, ẹlẹkọ ọrun yoo polowo.

Arabinrin Rasheedat sọ pe ohun to kọ awọn mọlẹbi lominu ni pe alaafia ara Rahamọn yii ko kun to, o ni aisan ọgbẹ ọkan (Ulcer), eyi gan-an ni ko jẹ ko le ṣiṣẹ agbara mọ niluu Ilọrin, to si lọọ ba awọn ẹgbọn rẹ ni oko l’Omu-Aran.

Leave a Reply