Famuyibọ fẹgbẹ APC silẹ l’Ekiti, o loun fẹẹ dije ninu ẹgbẹ Akọọdu

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Oludije tẹlẹ ninu ẹgbẹ Social Democratic Party, Oloye Reuben Famuyibọ, ti fẹgbẹ Onigbaalẹ nipinlẹ Ekiti silẹ, pẹlu ileri pe oun yo dije ninu ẹgbẹ Akọọdu ninu eto idibo gomina ti yoo waye nipinlẹ naa ninu oṣu kẹfa, ọdun yii.

Famuyibọ ṣalaye pe igbesẹ oun lati fi ẹgbẹ Onigbaalẹ silẹ ati lati dije ninu ẹgbẹ miiran waye pẹlu bi awọn eeyan ipinlẹ naa ṣe n pe oun pe afi dandan ki orukọ oun wa ninu iwe idibo gomina ninu eto idibo to bn bọ lọna naa.

Ọkunrin yii jẹ ọkan lara awọn oludije funpo gomina ninu ẹgbẹ APC lọdun 2018. Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ l’Ado-Ekiti l’Ọjọruu, Wesidee, ọsẹ yii, o sọ pe awọn adari ẹgbẹ APC l’Ekiti ko fi aaye silẹ fun ọmọ ẹgbẹ miiran lati kopa ninu itẹsiwaju ẹgbẹ naa.

O ṣalaye pe eleyii gan-an lo fa a ti awọn alatilẹyin oun fi sọ pe ki oun maa lọ sinu ẹgbẹ miiran lati lọọ dije fun ipo gomina naa.

Ọmọ bibi ilu Ado-Ekiti yii sọ pe wọn ti pinnu lati fi idibo abẹle ẹgbẹ naa ṣe ojusaaju fun ẹni ti gomina ipinlẹ naa, Dokita Kayọde Fayẹmi, ba fa kalẹ. O ni eleyii ni ko fun oun laaye lati tẹsiwaju pẹlu ipinnu oun lati di gomina ninu ẹgbẹ APC.

O ṣalaye pe oun ti bẹrẹ iwadii ijinlẹ (Research) bi oun yoo ṣe ṣejọba onitẹsiwaju ti yoo ko gbogbo ọmọ ipinlẹ Ekiti jade ninu oṣi ati aini, ni kete ti wọn ba kede oun gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori ninu eto idibo naa ti yoo waye lọjọ kejidinlogun, ọṣu kẹfa.

Famuyibọ sọ pe awọn alatilẹyin oun ti bẹrẹ ipolongo olojule si ojule ni gbogbo ijọba ipinlẹ merindinlogun to wa nipinlẹ Ekiti.

 

Leave a Reply