Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Oluwoo ti ilẹ Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ti sọ pe ọna kan ṣoṣo ti opin fi le de ba iwa gbigbe oogun oloro, igbesunmọmi, ipaniṣowo ati ipaniyan ni ki Aarẹ orileede yii, Muhammed Buhari, fi aṣẹ idajọ iku mulẹ fun ẹnikẹni to ba dan iru ẹ wo.
Ninu atẹjade kan ti akọwe iroyin Oluwoo, Alli Ibraheem, fi sita l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, lo ti sọ pe bii igba ti eeyan fi ina sori orule sun ni ibi ti ọrọ eto aabo n lọ bayii, o si pọn dandan kijọba apapọ tete gbe igbesẹ lori ẹ.
Nipa ṣiṣe eyi, Oluwoo ni yoo jẹ ẹkọ nla fun awọn ti wọn ba tun n gbero lati hu iru awọn iwa bẹẹ.
O ni igboya ti awọn kan n ni lati gbe oogun oloro lo fa a ti awọn ti wọn n hu iwa igbesunmọmi fi n gbilẹ si i.
Oluwoo gba ijọba apapọ niyanju lati tete pakiti mọra, ki wọn si da eto igbogun ti iwa ibajẹ ti ijọba Tunde Idiagbọn ati Jẹnẹra Muhammed Buhari gbe kalẹ lọdun 1984, iyẹn War Against Indiscipline (WAI), pada.
O ni eto WAI to bẹrẹ loṣu kẹta, ọdun 1984, to si pari loṣu kẹsan-an, ọdun 1985, jẹ eyi to fopin si iwa jẹgudujẹra lorileede yii, ti eto aabo ko si mẹhẹ bii eleyii.
O fi kun ọrọ rẹ pe ijọba gbọdọ kọju ija si awọn to n fi iwa igbesunmọmi, ipaniṣowo, iwa-ipa gbogbo, ṣiṣẹ ṣe nipa fifun wọn ni idajọ iku, ki alaafia le wa lawujọ wa.
Oluwoo ṣalaye pe awọn oogun oloro ti wọn n gbe lo n sọ wọn di alailaaanu lawujọ, o si buru pe orileede Naijiria ti di ibuba oogun oloro nitori ijọba ti pa idajọ iku ti fun wọn.
O ni bi igbesunmọmi ṣe n gbilẹ si i ni apa Ariwa orileede yii ni iwa ipaniṣowo n gbilẹ si i ni apa Guusu, ẹjẹ awọn alaiṣẹ si n ṣan lojoojumọ, ko si si bi ọjọ kan ṣe le kọja lai gbọ iroyin buburu lorileede yii.
Ọba Akanbi ni ijọba gbọdọ jigiri si ojuṣe wọn ki nnkan too bọ sori, ki wọn si gba awọn iran to n bọ ninu wahala.