Faith Adebọla
Ṣe ẹ ranti Abdulkadir Saliu, Seriki Fulani ilu Igangan, lagbegbe Ibarapa, Oke-Ogun, nipinlẹ Ọyọ, ti Oloye Sunday Adeyẹmọ tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho fun ni gbedeke ko filu Igangan silẹ lọdun 2021, latari akọlu leralera tawọn afurasi Fulani darandaran n ṣe sawọn agbẹ agbegbe naa lọjọsi?
Abdulkadir ti sọ poun o fara mọ bawọn kan ṣe n beere fun itusilẹ Sunday Igboho kuro lahaamọ awọn agbofinro orileede olominira Benin ti wọn fi i si lati oṣu keje, ọdun to kọja, ati pe, o da oun loju pe niṣe ni Sunday Igboho yoo ma ge ika abamọ jẹ bayii fun lile to le oun jade kuro niluu Igangan, tawọn ẹmẹwa rẹ si tun ṣakọlu soun.
Ninu ọrọ kan to ba awọn iweeroyin Daily Trust sọ lọjọ Ẹti to kọja yii, Seriki Fulani naa ni ko sigba toun ba ranti ohun toju oun ri, paapaa lasiko akọlu to waye ni ọjọ kejilelogun, oṣu ki-in-ni, ọdun 2021 naa, ti omije ẹkun ki i gbọn oun, iṣẹlẹ toun o le gbagbe lae ni.
“O wa lakọọlẹ pe ọmọ Yoruba mẹta pere ni wọn ji gbe niluu Igangan latigba ti wahala ọhun ti bẹrẹ, ẹya Fulani ni gbogbo awọn yooku ti wọn n ji gbe.
“Inu iṣẹlẹ yẹn ni aburo mi doloogbe si. Ọpọ awọn eeyan wa ni wọn pa danu. Maaluu ti wọn ji, to sọnu tabi ti wọn ṣe baṣubaṣu ko niye. Ọrọ ibanujẹ gidi ni fun mi. Gbogbo ohun ti mo fowurọ aye mi ko jọ ni mo padanu lasiko akọlu ti Sunday Igboho ṣe si Gaa wa yẹn. Atigba naa ni aye ti nira fun mi titi dasiko yii.
“O da mi loju pe oun (Sunday Igboho) naa yoo ti maa geka abamọ jẹ fun ohun to ṣe yẹn bayii. Ko si ibi ti ọmọ Naijiria eyikeyii ko le gbe lorileede yii, gbogbo igba ni mo si ti maa n sọ pe awọn ọdaran wa kaakiri ni. Bi ọdaran ṣe wa ninu awọn ọmọ Yoruba naa lo wa laarin awa Fulani. Idi niyẹn to fi yẹ kijọba ṣiṣẹ lati wa awọn to jẹ ọdaran gan-an lawaari, ki wọn si fi wọn jofin.
“Mi o faramọ ki wọn tu Sunday Igboho silẹ lahaamọ, ko si dun mọ mi bawọn eeyan ṣe n beere pe kijọba tu u silẹ. Iya toun ati awọn ẹmẹwa ẹ fi jẹ mi kọja afẹnusọ, mo si fẹ ki idajọ ododo waye lori ọrọ naa.
“Loootọ ni Sunday Igboho fun mi ni gbedeke lati filu silẹ nigba yẹn, mi o si ko iyan ọrọ naa kere, ṣugbọn nigba ti mo lọọ fẹjọ sun awọn agbofinro, wọn fi mi lọkan balẹ pe ko sewu, pe kinni kan ko le ṣẹlẹ si mi. Loootọ lọjọ naa, awọn ọlọpaa bii mẹrinla ni wọn ko wa lati pese aabo, bi awọn ọmọọṣẹ Sunday Igboho ṣe bori wọn jọ mi loju.
“Ko sohun meji ti mo fẹ bayii ju idajọ ododo lọ.” Bẹẹ ni Seriki Fulani naa sọ.