Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti tẹ awọn ogboju adigunjale ti ko din ni mejila, ti wọn n gbogun ti ipinlẹ naa lati igba diẹ sẹyin.
Gẹgẹ bi Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ naa, Ọgbẹni Tunde Mobayọ, ti Alukoro wọn, Ọgbẹni Sunday Abutu, gbẹnu sọ fun ṣe ṣalaye, o ni ni ogunjọ, oṣun kin-in-ni, ọdun yii, ni awọn adigunjale naa ti ko din ni mejila ya bo ile awọn ọmọ obinrin ile iwe giga Poli to wa loju ọna ileewe naa, ti wọn si gba owo, foonu ati awọn dukia miiran to jẹ ti awọn ọmọ ileewe giga naa.
Abutu sọ pe lọgan ti awọn ọlọpaa gbọ nipa iṣẹlẹ naa ni wọn gbera lati ṣe itọpinpin wọn, ṣugbọn awọn adigunjale naa ti kuro ni ibi iṣẹlẹ ọhun. Lẹyin itọpinpin awọn ọlọpaa lọwọ tẹ meji lara awọn adigunjale naa ti orukọ wọn n jẹ, Damilọla Christopher ati Oyedele Oluwatobi, ti wọn si ba foonu ati dukia ti wọn ji ni ilegbee awọn ọmọ akẹkọọ naa lọwọ wọn.
Bakan naa, ninu itọpinpin awọn ọlọpaa siwaju si i, ọwọ tun tẹ mẹrin ninu awọn adigunjale naa, Ojo Tọpẹ, Aderọpo Temitọpẹ, Ẹkundayọ Ajibọla ati Ojo Bello, nibi ti wọn fara pamọ si ni adugbo Falana, to wa ni agbegbe Ajilosun, l’Ado-Ekiti.
Bakan naa ni wọn tun ba awọn ẹru ti wọn ji ninu ile awọn akẹkọọ naa lọwọ wọn.
Nigba ti awọn ọlọpaa n fi ọrọ wa wọn lẹnu wo, awọn ọdaran naa jẹwọ pe loootọ lawọn digun ja awọn ọmọleewe naa lole. Wọn ni lara awọn ọmọ ẹgbẹ tawọn jọ maa n jale ni Giwa Tosin, Adegoke Joshua, Solomon Noah, Oguntoye Tajudeen ati Olatuyi Tunde. Ile ti ko din ni mẹrindinlọgọrun-un ni awọn eeyan naa ti jale kaakiri ipinlẹ Ekiti.
Abutu sọ pe wọn ti digun jale ni agbegbe bii Embassy Island, Ajabande, Oju Ọna Poli atawọn agbegbe miiran bii Agogo, ni Ilupeju Avenue, nibi ti wọn ti pa ọmọdekunrin kan torukọ rẹ n jẹ Blessing Joseph to jẹ ọlọdẹ alẹ ni agbegbe naa.
O ṣalaye pe wọn tun pa ọlọdẹ alẹ kan ni Ilawẹ-Ekiti, ninu oṣu kejila, ọdun to kọja yii. Bakan naa ni won tun jẹwọ pe awọn pa ọkunrin oni POS kan torukọ rẹ n jẹ Apata Ọlabọde, ti wọn si tun ni awọn fipa ba ọmọdekunrin kan lo pọ ni adugbo Irewọlede, l’Ado-Ekiti.
Alukoro ọlọpaa yii ni iwadii fihan pe gbogbo awọn ọdaran ti ọwọ wọn tẹ naa ni wọn ṣẹṣẹ dari de lati ọgba ẹwọn. O fi kun un pe wọn yoo foju bale-ẹjọ ti iwadii ba pari lori ọrọ wọn.