Jọkẹ Amọri
Bi ki i baa ṣe ọpẹlọpẹ awọn ọlọpaa ayaraṣaṣa ti wọn n pe ni RRS, ri wọn tete debẹ, o ṣee ṣe ki ọmọbinrin ti o wa ninu aworan yii ti bẹ somi, ko si ti gbabẹ ku. Alagbalugbu omi Ọsa to wa ni opin Iyana Oworo, ni wọn ni ọmọbinrin naa fẹẹ kan lu, ti ikọ ayaraṣaṣa (RRS) fi ṣi i lọwọ, ti wọn ko si jẹ ko bẹ somi gẹgẹ bo ṣe fẹẹ ṣe.
ALAROYE gbọ pe ọkunrin to n wa ọkada lọ lo ṣakiyesi ọmọbinrin naa, to si pe akiyesi awọn RRS si i. Awọn eeyan naa ni wọn sun mọ ọn, ti wọn ko si jẹ ko bẹ lumi.
Nigba ti wọn beere idi to fi fẹẹ ko somi, o ni nitori pe wọn ba oun wi nile loun ṣe fẹẹ binu ko sodo, ki oun si para oun danu.
Oju-ẹsẹ ni wọn ti gbe e lọ si agọ ọlọpaa to wa ni Iyana Oworo, nigba ti wọn n sa ipa lati ri awọn eeyan rẹ.