Ladọja atawọn agba ijoye Ibadan ti yan Balogun gẹgẹ bii ọmọ oye Olubadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Nnkan ti ṣenuure bayii fun Ọtun Olubadan ilẹ Ibadan, Sẹnetọ Lekan Balogun, lati gori itẹ gẹgẹ bii Olubadan ilẹ Ibadan tuntun.

Eyi ko ṣẹyin ipade ti awọn agbalagba ijoye ilu naa ṣe, ninu eyi ti wọn ti panu-pọ yan Balogun gẹgẹ bii ẹni ti ipo ọba tọ si bayii.

L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹta, oṣu keji, ọdun 2022 yii, ni wọn fẹnu ọrọ naa jona ninu ipade ti wọn ṣe nile Balogun ilẹ Ibadan, Agba-Oye Owolabi Olakulẹyin.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, ijọba ipinlẹ Ọyọ lo ṣeto ipade naa, nitori oludari eto iṣakoso ijọba ibilẹ Ila-Oorun Guusu Ibadan wa ninu apero ọhun pẹlu wọn lati ṣoju ijọba ipinlẹ yii.

Awọn Agba ijoye to kopa ninu ipade ọhun ni Senetọ Balogun funra ẹ; Agba-Oye Owolabi Ọlakulẹyin tii ṣe Balogun ilẹ Ibadan; Tajudeen Ajibola; (Ọtun Balogun); Agba-Oye Eddy Oyewọle (Asipa-Olubadan) Eddy Oyewọle;  Lateef Gbadamọsi Adebimpe (Osi Balogun); Kọlawọle Adegbọla (Ashipa-Balogun) ati Agba-Oye Dada Iṣioye ti i ṣe Ẹkẹrin Balogun ilẹ Ibadan.

Ẹni ti ijokoo rẹ jọ gbogbo aye loju ju ninu awọn agba ijoye yii ti wọn tun jẹ Afọbajẹ ilẹ Ibadan ni Osi Olubadan ilẹ Ibadan, Sẹnetọ Rashidi Ladọja, ẹni tí ki i ba wọn kopa ninu awọn ìpàdé tí wọn ti maa n ṣe latigba ti Olubadan ana, Ọba Saliu Adetunji, ti waja, nitori to lodi si oye ọba ti ijọba Oloogbe Ajimọbi tii ṣe gomina àná ni ipinlẹ yii fi wọn jẹ lọdun 2017.

Leave a Reply