Adewumi Adegoke
Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun wọ awọn ọmọde keekeeke ti wọn bẹ ori ọrẹbinrin ọkan ninu wọn pẹlu erongba lati fi ṣoogun lọ si ile-ẹjọ giga kan ni Isabo, niluu Abẹokuta, nipinlẹ Ogun.
Awọn mẹrẹẹrin ọhun, Balogun Mustakeem, Majẹkodunmi Sọliudeen, Abdul Gafar Lukmon ati Majẹkodunmi Ọladẹhinde ni wọn wọ wa siwaju Onidaajọ I.O Abudu pẹlu iwe ipẹjọ to ni nọmba MISC 22/2022. Ẹsun meji ọtọọtọ ti wọn fi kan wọn niwaju adajọ ni ẹsun ipaniyan ati igbiyanju lati paayan.