Nitori wahala ijaabu to mu ẹmi akẹkọọ kan lọ, ijọba ti ileewe girama kan pa ni Kwara 

O kere tan, ọmọleewe kan lo ku, ti ọpọ si fara pa yannayanna, lasiko ti awọn ọmọ ileewe Baptist High School, nijọba ibilẹ Ọyun, niluu Ijagbo, n ṣe iwọde wọọrọwọ ninu ọgba ileewe naa l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii.

ALAROYE gbọ pe lasiko ti wọn n ṣe iwọde ifẹhonuhan lori pe awọn alaṣẹ ileewe naa yari kanlẹ pe awọn ko faaye gba ki awọn ọmọ Musulumi maa lo ijaabu ninu ọgba ileewe ọhun. Nibi ti wọn ti n ṣe iwọde lọwọ ni awọn janduku kan ti lọọ ṣe akọlu si wọn, to mu ki akẹkọọ kan, Habeen Mustapha, pade ọlọjọ rẹ, ti ọpọ awọn ọmọ ileewe ọhun si fara pa yannayanna. Lati ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kin-in-ni, ọdun yii, ni wọn sọ pe gbọnmi si i, omi o to o, ti n waye ninu ọgba ileewe ọhun latari pe awọn alaṣẹ sọ pe awọn ọmọ Musulumi lobinrin ko gbọdọ lo ijaabu ninu ọgba ileewe naa mọ, ti awọn obi awọn Musulumi ileewe naa si fariga pe ileewe ijọba ni, wọn o le fofin de ọmọ awọn lati lo ijaabu wọn, eyi to mu ki ijọba da si i, to si ni ọmọ to ba wu le lo ijaabu lawọn ileewe ijọba gbogbo nipinlẹ Kwara.

Ni bayii, ijọba ipinlẹ Kwara ti bẹnu atẹ lu iṣẹlẹ naa, o si ti paṣẹ pe ki wọn ti ileewe naa pa kiakia titi di ọjọ ainigbendeke.

 

Leave a Reply