Faith Adebọla
Gomina ipinlẹ Jigawa tẹlẹ, to tun jẹ agba ọjẹ ọmọ ẹgbẹ PDP (Peoples Democratic Party) l’Oke-Ọya, Alaaji Sule Lamido, ti sọ pe oun ko fara mọ bawọn eeyan kan ṣe n pariwo pe agbegbe kan pato lo kan lati mu aarẹ jade, tabi pe ki wọn pin ipo naa sapa ibikan lorileede yii, o ni iru eto bẹẹ ko daa fun itẹsiwaju iṣakoso demokiresi nilẹ wa, bii ẹni da ọwọ aago itẹsiwaju pada sẹyin fun Naijiria ni.
Lamido sọrọ yii lọjọ Satide, Abamẹta, ọsẹ yii, lasiko to n dahun ibeere tawọn oniroyin bi i lori erongba rẹ nipa eto oṣelu ilẹ wa.
O niṣe lo yẹ kawọn ẹgbẹ oṣelu ati awọn aṣaaju ilẹ wa ṣiṣẹ fun iṣọkan ati itẹsiwaju Naijiria, ki i ṣe apa ibi ti aarẹ ti maa wa lo yẹ ko jẹ wọn logun, ṣugbọn bi ẹni yoowu ko di aarẹ yoo ṣe mu ilọsiwaju ba ilẹ wa.
“Ẹnikẹni to ba ṣetan lati fi tọkantọkan ṣiṣẹ fun ilọsiwaju Naijiria la gbọdọ gbaruku ti, ka si fun tọhun niṣiiri, lai ka ibi yoowu ko ti wa si. Ko seyii to kan mi nipa ẹya, iran, ede tabi agbegbe ibi to ti wa, koda ẹsin rẹ ko ṣe pataki to bẹẹ.
“Ẹ jẹ ka wo bi orileede wa ṣe ri lonii, ki lanfaani ta a ti ri gba ninu pinpin ipo aarẹ sagbegbe kan? Ṣe o ti sọ agbegbe naa di daadaa yatọ sawọn to ku ni?”
Bakan naa ni Lamido bẹnu atẹ lu igbesẹ ijọba apapọ lati mu owo iranwọ ori epo bẹntiroolu kuro, o ni:
“Niṣe lẹrin maa n pa mi ni gbogbo igba ti mo ba n ronu lori ọrọ yiyọ owo iranwọ ori epo bẹntiroolu kuro, eyi tijọba Muhammadu Buhari yii gun le. Ko sọrọ abuku ti Buhari ati ẹgbẹ oṣelu APC (All Progressives Congress) rẹ ko sọ tan sawọn ijọba to kọja lori ọrọ yii, igba kan wa ti wọn tiẹ sọ pe arumọjẹ ni owo iranwọ naa, pe ko sohun to n jẹ bẹẹ, pe niṣe nijọba apapọ fi n lu awọn ọmọ Naijiria ni jibiti lasan, ati bẹẹ bẹẹ lọ, ṣugbọn ẹ wo wọn lonii bayii.
“Ọkunrin yii (Buhari), ṣe olori Naijiria ni nnkan bii ogun ọdun sẹyin, o ṣe minisita lori ọrọ epo rọbi, sibẹ ṣe o ṣi n sọ fun wa poun ko mọ nnkan ti sọbusidi (subsidy) lori epo jẹ ni, tabi pe ko ye oun mọ ni. Ṣe ẹ ti waa ri i bayii pe irọ nla nla ni wọn n pa fawọn ọmọ Naijiria lati fi wa ibo lasiko kampeeni wọn igba yẹn? Ṣugbọn otitọ ti foju han bayii.”
Bẹẹ ni Lamido sọ.