Afi ki ijọba ipinlẹ Ogun atawọn tọrọ kan tete wa nnkan ṣe si iwa ọdaran to ti n di lemọlemọ nipinlẹ naa bayii.
O fẹrẹ ma si ojumọ kan ti wọn ko ni i ri ẹsun ipaniyan, ijinigbe ati ifiniṣowo kan tọka si nipinlẹ ọhun laarin ọsẹ kan.
Ni bayii, ileeṣẹ eto aabo ti wọn n pe ni So-Safe ti tun mu ọmọkunrin kan ti wọn pe ni Sunday Alani pẹlu ọmọ ti ko ti i ju ọdun kan ataabọ lọ to ji gbe, to si ti jẹwọ pe ibi ti awọn ti fẹẹ lọọ fi ọmọ naa ṣooogun owo loun n gbe e lọ tọwọ fi tẹ oun l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii, ni ikọ So-Safe, Moruf Yusuf, ṣalaye fawọn oniroyin pe lasiko tawọn n yide kaakiri lọwọ tẹ ọkunrin naa ni Abule Tọlaṣẹ, nijọba ibilẹ Ọdẹda, nipinlẹ Ogun, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja yii, lasiko to fẹẹ maa gbe ọmọ ọdun kan aabọ naa sa lọ.
Alukoro yii ni awọn ikọ So-Safe to wa niluu Ilugun ti fi ọrọ wa Alani lẹnu wo, o si ti jẹwọ pe loootọ loun ji ọmọ naa, ati pe ọdọ awọn ẹgbẹ oun tawọn jọ maa n fi eeyan ṣetutu owo loun n gbe e lọ kọwọ too tẹ oun.
Kaadi ti wọn fi n gbowo lẹnu ẹrọ ati foonu kan ni wọn ba lọwọ rẹ, eyi ti Yusuf ni awọn ti ko ranṣẹ si olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Ọdẹda.