Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ.
Lati ọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii ni ilu Idanre ti n gbona janjan latari ija tawọn oloṣelu n ba ara wọn ja lori eto idibo ijọba ibilẹ to fẹẹ waye ni ipinlẹ Ondo lọjọ Abamẹta, Satide, yii.
O kere tan awọn eeyan bii mẹwaa ni wọn fara pa lasiko akọlu to waye laarin ọjọ meji ọhun ti gbogbo wọn si wa ni ile-iwosan ti wọn ti n gba itọju lọwọ.
Ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ SDP to b’ALAROYE sọrọ ni ipade lawọn n ṣe lọwọ ni olu ile ẹgbẹ awọn to wa ni Agọsile, Odode-Idanre, nigba tawọn tọọgi bii ọgbọn deede ya bo awọn lojiji pẹlu awọn nnkan ija bii ada ada, aake ati ọpọlọpọ okuta lọwọ wọn.
O lawọn tọọgi naa ko woju ẹnikẹni, ẹni ti wọn ba ti ri lo ni wọn n ṣa ladaa ati aake ti wọn si tun fi oko ṣe ọpọ awọn eeyan leṣe.
Gbogbo patako ti wọn ya aworan awọn oludije ẹgbẹ SDP si eyi to wa lojuko ipade ọhun lo ni wọn bajẹ patapata.
Ọgbẹni Bankọle Akinṣelurẹ to n dije dupo alaga ijọba ibilẹ Idanre naa fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O ni loju ẹsẹ ti akọlu yii ti bẹrẹ lawọn ti sare pe awọn ọlọpaa to wa ni tesan Ọlọfin.
Ọgbẹni Akinṣelurẹ ni iyalẹnu nla lo jẹ fawọn nigba tawọn agbofinro wọnyi de ti wọn si n wo awọn tọọgi naa bi wọn ṣe n pa itu ọwọ wọn laiṣe ohunkohun nipa rẹ.
Oludije ọhun ni oun mọ pe oun gan-an lawọn janduku naa tori ẹ wa ṣe akọlu ti wọn waa ṣe, ki Ọlọrun too ko oun yọ lọwọ wọn.
Nigba t’ALAROYE kan si Tee-Leo Ikoro to jẹ alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo lati fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, esi to fun wa ni pe ko sẹni to ti i fi ọrọ naa to oun leti.
Olopa naija