Adewumi Adegoke
Olu ileeṣẹ ẹgbẹ awọn onimọto nilẹ wa ti fiwe waa sọ tẹnu ẹ ranṣẹ si Alaga awọn onimọto nipinlẹ Eko, Musiliu Akinsanya ti gbogbo eeyan mọ si MC Oluọmọ. Eyi ko sẹyin awọn iwa kan ti wọn lo hu to lodi sofin ati agbekalẹ ẹgbẹ naa, bẹẹ ni wọn si lo ri awọn aṣaaju ẹgbẹ fin.
Ninu iwe ti wọn fi ranṣẹ naa ti wọn kọ lọjọ kẹrinla, oṣu Keji, ọdun yii, eyi ti Akọwe ẹgbẹ naa, Kabiru Yau, fọwọ si sọ pe Oluọmọ kọ lati mu aṣẹ ti olu ile ẹgbẹ yii pa fun un ṣẹ.
Apa kan lẹta naa ka pe ‘‘Wọn ti pe akiyesi wa si i pe bo tilẹ jẹ pe akọwe apapọ ẹgbẹ wa ran ọ lati ṣe awọn nnkan kan lasiko ti a ṣe ipade pẹlu iwọ ati awọn ọmọ igbimọ rẹ nipinlẹ Eko niluu Abuja lọjọ kẹsan-an, oṣu Keji, ọdun yii, nipa yiyan Alaaji Azeez Abiọla gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ awọn oni Marwa nipinlẹ Eko, o ko tẹle aṣẹ yii. Dipo ki o tẹle aṣẹ yii, niṣe lo gun le hihalẹ, didẹruba ati lilu alaga ti wọn ṣẹṣẹ yan naa.’’
Bakan naa ni olu ileeṣẹ wọn yii fẹsun kan Oluọmọ pe o kọ lati fa ile ẹgbẹ onimọto tẹlẹ to wa ni 360, Abule-Ẹgba, loju ọna marosẹ Eko si Abẹokuta, nipinlẹ Eko, fun awọn ọmọ igbimọ oni kẹkẹ Marwa yii, pẹlu ero lati ma jẹ ki wọn le maa lo ibẹ.
Bakan naa ni wọn tun fẹsun kan MC pe o n lo awọn tọọgi lati maa gba gareeji awọn to jẹ ọta rẹ. Wọn ni eleyii wa lakọọlẹ pe o ran awọn tọọgi lọ si awọn gareeji to jẹ ti awọn ọta rẹ lati da wahala silẹ nibẹ.
‘‘Nitori awọn aṣemaṣe yii, o gbọdọ fa olu ileeṣẹ awọn onimọto tẹlẹ yii kalẹ laarin wakati mejidinlaaadọta fun igbimọ awọn oni kẹkẹ Marawa ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan.
‘‘Ki o ko gbogbo awọn ti o ran lọ si awọn ẹka yin ti awọn ti o ro pe ọta rẹ ni wọn wa kuro. Ki o si kọ iwe lati tọrọ aforiji si olu ileeṣẹ ẹgbẹ onimọto
‘‘Bi o ba kọ lati tẹle gbogbo awọn aṣẹ yii, ẹgbẹ ko ni i ni ohun mi-in lati ṣe fun ọ ju pe ka gbe igbesẹ to ba yẹ lori ni ilana ofin ati alakalẹ ẹgbẹ lori rẹ.’’
ALAROYE pe Agbẹnusọ fun MC Oluọmọ, Jimoh Buhari, lati mọ iha ti ọga rẹ kọ si ọrọ naa, ohun to sọ ni pe MC Oluọmọ maa fesi si iwe waa wi tẹnu ẹ ti wọn fun un. Ṣugbọn ko si nile lasiko yii. O maa dahun si i to ba ti de.