Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ori lo ko Ọba ilu Ayede-Ekiti, Adelẹyẹ Orisagbemi, yọ lọwọ iku ojiji lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, nigba ti awọn agbebọn kan ti wọn ko ti i mọ kọ lu ọba alaye yii.
Iṣẹlẹ nla yii ṣẹlẹ loju ọna to lọ lati Iṣan-Ekiti si Ayede-Ekiti, ni deede agogo mẹsan-an alẹ, nigba ti ọba naa n pada bọ lati Ipade kan to lọọ ṣe ni Ijero-Ekiti.
Gẹgẹ bi awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣe sọ, wọn ni awọn agbebọn naa ni fẹẹ ji ọba alaye naa gbe ni, ṣugbọn ori ko o yọ, eleyii lo fa a ti wọn fi doju ibọn kọ ọkọ ọba naa.
Titi di igba ti a fi n ko iroyin yii jọ, ọba alaye naa ti wa nileewosan kan niluu Ado-Ekiti, nibi to ti n gba itọju.
Gbogbo akitiyan wa lati ba kabiyesi sọrọ lo ja si pabo pẹlu bi ẹrọ ilewọ rẹ ko ṣe lọ. Ṣugbọn nigba to n sọrọ lori ọrọ naa, Alukoro ileeṣẹ ọlọpa ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọ pe oun ti gbọ nipa iṣẹlẹ naa.
O ni kabiyesi n bọ lati Ijero-Ekiti ni, nibi to ti lọọ ṣe ipade kan nigba ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, o fi kun un pe awọn ọlọpaa ti n sa gbogbo ipa wọn lati mu awọn agbebọn to wa nidii iṣẹlẹ naa.
O ṣalaye pe kabiyesi naa ti wa nileewosan aladaani kan niluu Ado-Ekiti, nibi to ti n gba itọju.