Gbenga Amos, Abẹokuta
Adajọ ile-ẹjọ giga kan to wa ni Isabo, niluu Abẹokuta, Onidaajọ I. A Abudu, ti paṣẹ pe ki wọn maa ko tọkọ-tiyawo ti wọn fẹsun ipaniyan kan, Kẹhinde Ọladimeji, ẹni ọdun mẹtalelogoji (43), ati Adejumọkẹ Raji, ẹni ọdun marundinlogoji, ti wọn n gbe ni No 72, Abiọla Way, Leme, Abẹokuta, lọ si ọgba ẹwọn to wa ni Ọba ati eyi to wa ni Ibara, nipinlẹ Ogun, titi di ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ti igbẹjọ yoo tun waye lori keesi wọn.
Awọn tọkọ-taya naa ni wọn gbimọ-pọ, ti wọn pa ọrẹ iyawo torukọ rẹ n jẹ Ifẹ Adeh, ẹni ọdun mejilelogun, ti wọn si ge ẹya ara rẹ kelekele, ti wọn ta ori rẹ fun ọkunrin kan ni ẹgbẹrun lọna aadọrin Naira.
Agbefọba to wa nidii ẹjọ naa, Oluwatosin Jackson, ṣalaye niwaju adajọ pe ọjọ kejila, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, ni awọn eeyan naa ṣẹ ẹṣẹ ọhun nile wọn to wa ni adugbo Lẹmẹ. Niṣe ni Adejumọkẹ pe ọmọbinrin to jẹ ọrẹ rẹ yii wa sile wọn pe ko waa ki oun. Lo ba se Indomine fun un. Ṣugbọn o ti fi oogun oorun sinu Indomine naa.
Lasiko ti ọmọbinrin na sun lẹyin to jẹ Indomine tan ni ọrẹ rẹ yii yin in lọrun, to si pa a. Lẹyin naa lo ge ara rẹ ni bur̀e burè, to si ta ori rẹ fun ọkunrin kan to maa n fi eeyan ṣe oogun owo niluu Ibadan.
Agbefọba ni oorun buruku to n jade lati inu yara awọn tọkọ-tiyawo yii lawọn araadugbo gbọ ti wọn fi lọọ ta awọn ọlọpaa lolobo tọwọ fi tẹ wọn.
Jackson ni iwa ti awọn eeyan naa hu lodi sawọn abala kan ninu ofin ipinlẹ ogun ti wọn ṣe lori iwa ọdaran ti ọdun 2006.
Onidaajọ I.O Abudu ko fi akoko ṣofo rara to fi ni ki wọn maa gbe awọn tọkọ-taya naa lọ si ọgba ẹwọn to wa ni Ọba, ati eyi to wa ni Ibara, niluu Abẹokuta, titi ti wọn yoo fi ri imọran gba lọdọ ileeṣẹ to n gba kootu nimọran.